Taofeeq lẹdi apo pọ mọ awọn oṣiṣẹ banki lati lu awọn eeyan ni jibiti owo nla lOṣogbo
Florence Babaṣọla
Ọmọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Adepọju Taofeeq Ọlalekan, ti fara han niwaju adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lori ẹsun pe o lu awọn eeyan ni jibiti.
Eeyan ọgọjọ o le mẹfa (186) la gbọ pe Taofeeq lu ni jibiti owo to to miliọnu marundinlaaadọta naira (#45m) laarin ọdun 2012 si oṣu keje, ọdun 2015.
Agbefọba, ASP Fagboyinbo Abiọdun, sọ funle-ẹjọ pe ṣe ni Taofeeq lọọ ba awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Ọṣun, o ṣeleri lati duro bii alagata ti yoo maa da owo ti wọn ya nileefowopamọ First Bank pada.
O n gba owo naa lọwọ wọn diẹdiẹ titi to fi wọ miliọnu lọna marundinlaaadọta naira ko too di pe awọn eeyan naa fura pe ṣe lo n lu awọn ni jibiti, ti wọn si fa a le awọn agbofinro lọwọ.
Nigba ti wọn ka ẹsun mẹrẹẹrin si i leti, olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi, bẹẹ naa ni agbẹjọro rẹ, S. P. Ogundari, bẹ kootu lati fi aaye beeli silẹ fun un lọna irọrun.
Adajọ M. A. Awodele faaye beeli silẹ fun un pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduuro meji. O ni awọn oniduuro naa gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba ti wọn si wa nipele owo-oṣu kẹẹẹdogun.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu keji, ọdun 2021.

Leave a Reply