Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọdaran ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Ademọla Adebukọla, ẹni tawọn eeyan tun mọ si ‘Holy Ghost’, ti rẹwọn oṣu mẹfa he niluu Ilọrin fẹsun ṣiṣe jibiti fun obinrin oyinbo kan lori ẹrọ ayelujara.
Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu tile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara lo ju ọdaran naa sẹwọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, nigba ti EFCC wọ ọ lọ sile-ẹjọ.
Akinpẹlu ni ẹwọn Ademọla yoo bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, tọwọ tẹ ẹ.
Ile-ẹjọ tun ni ọdaran naa yoo padanu foonu iPhone 5 ati ẹrọ kọmputa alaagbeka to fi n lu jibiti.
Ademọla ni wọn lo n tan Sherri Reed pe oun nifẹẹ rẹ, to si ni ki iyẹn fi owo dọla ẹgbẹrun mẹta ati ọgọrun-un marun-un, $3,500 ranṣẹ soun lati fi gba awọn ọja kan.
Bakan naa, ọdaran ọhun tun lo ayederu orukọ kan lati fi lu obinrin mi-in, Wanda Smith, ni jibiti ninu oṣu keje, ọdun 2020.