Ọkan ninu awọn tina jo l’Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun ti ku o

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Ọsibitu ‘Federal Medical Center’(FMC), l’Abẹokuta, ti fidi ẹ mulẹ pe ọkan ninu awọn tina jo nibi ijamba to ṣẹlẹ ni Kutọ l’Abẹokuta, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ti dagbere faye.

Agbẹnusọ ọsibitu yii, Ọgbẹni Ṣẹgun Orisajo, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii.

O ṣalaye pe ọkunrin ni ẹni ọdun mejilelogoji to doloogbe naa. Orisajo ṣalaye pe ina jo ọkunrin naa pupọ, ida mẹrindinlọgọrun-un (96%) lo pe apa ibi ti ina ti jo o.

O tẹsiwaju pe nigba ti wọn gbe e de pẹlu awọn meji mi-in ti ina yii jo, awọn n fa omi ti oogun wa ninu rẹ si wọn lara gẹgẹ bi ọna itọju kan ni. Nigba ti ọkunrin naa ni iṣoro ati tọ, awọn bẹrẹ eto lati ṣe itọju ti wọn n pe ni ‘Dialisis’ fun un, ṣugbọn aarọ Ọjọbọ yii lo ku ki wọn too ṣeto itọju naa fun un rara.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kin-in-ni yii, ni ina sọ lagbegbe banki GTB, ni Kutọ, l’Abẹokuta, lasiko ti tanka epo kan padanu ijanu ẹ nigba to fẹẹ sọkalẹ lori afara Kutọ.

Eeyan mẹta lo ku loju-ẹsẹ nibẹ, mọto ati ọkada jona, awọn mi-in si fara pa, wọn gbe wọn lọ si FMC, ọkan ninu awọn to fara pa lo dagbere faye yii.

Leave a Reply