Akikanju ọmọ ilẹ Yoruba nni, Sunday Igboho, ti sọ pe ki i ṣe pe oun ni i lọkan lati ri Ọọni Ileefẹ, Ọba Ogunwusi, fin, o ni oun n fi ọrọ naa ta wọn ji ni. O ni ọrọ naa ka oun lara ni, nitori oun wọnu igbo, oun si mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ. Bẹẹ lo ni ki i ṣe Ọba Ogunwusi nikan loun doju ọrọ naa kọ, o ni gbogbo awọn agbagbga ilẹ Yoruba loun n ba wi lati fi ta wọn ji si niNinu fidio kan to gbe jade to fi ṣalaye ọrọ ati bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lo ti sọrọ naa ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Igboho ni nilẹ Yoruba, ẹnu ọmọ ko gba iya padi mọ, ṣugbọn bi ọrọ naa ṣe ka oun lara, to si n dun oun loun fi sọrọ ti oun sọ yii. O ni bi awọn Fulani ajinigbe ṣe n paayan, ti wọn si n ji awọn eeyan gbe lo ka oun lara.