Ẹ nilo ilana ibilẹ lati gba ara yin loko ẹru Ilọrin- Oṣhogun Ile-Ifẹ

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Oṣhoogun tilu Ile-Ifẹ, Ọba Ọlafinranye Ọladapọ, ti gba awọn Yoruba nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, to n ja fun ominira labẹ oko ẹru ilu Ilọrin, lati fi ilana ibilẹ kun ọna ti wọn fi n ja ijangbara naa ki wọn le baa tete ri ọna lọ.

Oṣhogun to ṣoju Arole Oodua, Ooni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja kin-in-ni, nibi idanilẹkọọ kan to waye niluu Jẹbba, nipinlẹ Kwara, ni o dara bawọn araalu ṣe n gba ọna ofin ati alaafia ja fun ẹtọ wọn, ṣugbọn yatọ si ilana ẹsin igbalode ti wọn fi n ja fun ẹtọ wọn, wọn tun ni lati lo abalaye nipa bibẹ awọn ooṣa ati alalẹ lọwẹ ki wọn le tete bọ.

O ni oun ti gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn ọmọ Oodua to wa lagbegbe naa, oun yoo si gbe e tọ kabiyesi (Ooni Ifẹ) to ran oun niṣẹ.

Awọn ara Moro ni ẹru tawọn ṣe labẹ ilu Ilọrin ti to gẹẹ, ni bayii, ominira lawọn n kigbe fun.

 

Wọn fẹsun kan Emir Ilọrin pe o fi tipa mu ijọba ibilẹ Moro sabẹ isakoso Ilọrin, eyi ti wọn n pe ni Ilọrin Emirate Council, lati le maa gba gbogbo ẹtọ to ba tọ sijọba ibilẹ naa.

Nibi idanilẹkọọ ọlọdọdun kan ti ajọ Millenium Initiatives on Societal Values, MISSAVS, gbe kalẹ ni wọn ti sọrọ naa.

Wọn ni ilu Ọyọ ati Ile-Ifẹ lawọn ti ṣẹ wa, awọn si ti n gbe ilu fun ọpọlọpọ ọdun ko too di pe wọn da Ilọrin silẹ.

Awọn araalu naa sọ pe ara ọna ti Ilọrin fi n tẹ ori awọn ri, ti wọn si sọ awọn di ẹru labẹ wọn ni bi Ọba (Emir) Ilọrin, Ibrahim Sulu-Gambari, ṣe dina igbega awọn ọba Moro nitori ko le baa tẹsiwaju lati maa jẹ gaba lori wọn.

Wọn ni fun apẹrẹ, awọn oyinbo to sakoso Naijiria ti ṣaaju ṣe igbega fun Ọhọrọ tilu Ṣhao, lọdun 1919, atawọn ọba mi-in to fi mọ Emir Ilọrin, ṣugbọn o jẹ ohun to ba awọn lọkan jẹ bi ijọba to n mojuto ẹkun Arewa (Northern Regional Government) ṣe fagi le igbega naa.

Wọn ṣalaye siwaju pe lẹyin igba ti iyẹn ṣẹlẹ, ijọba Alhaji Adamu Attah ati Gomina Mohammed Lawal tun ṣe igbega fun Ọhọrọ tilu Ṣhao ati Ọba Jẹbba, ṣugbọn si iyalẹnu awọn, Gomina Bukọla Saraki, toun naa jẹ ọmọ Ilọrin, fagi le igbega awọn ọba naa lati le tẹ Emir Ilọrin lọrun.

Yatọ si eyi, awọn araalu ni iwa jibiti gbaa ni bijọba ṣe pin Moro si ẹkun Arewa (Kwara North) nilana oṣelu, ṣugbọn nitori ati tẹ ẹni kan lọrun ti wọn waa pin ijọba ibilẹ kan naa sabẹ Ẹmireeti Ilọrin to wa ni Aarin-Gbungbun Kwara (Kwara Central) lati le jẹ ki ọba Ilọrin maa gba ida marun-un ninu owo to n wọle sapo ijọba ibilẹ Moro loṣooṣu sapo ara rẹ.

Wọn ni lati aye ijọba Ọgagun Sanni Abacha tijọba apapọ ti bẹrẹ yiyọ ida marun-un fun awọn ọba ni ọba Ilọrin ti n gba owo naa, ti ko si jẹ ki adari ilu kankan nijọba ibilẹ Moro janfaani rẹ.

“Awọn Baalẹ ọgọrun-un kan le mẹrindinlogoji ni Oloru, Ipaiye, Malete, Eji Dongari ati Lanwa to wa nijọba ibilẹ Moro to yẹ ki wọn lẹtọọ si i ko janfaani owo naa.”

Ninu ọrọ tiẹ, oludanilẹkọọ ọjọ naa, Alagba Toyin Alabi, ni ṣaaju akoko yii, wọn ki i gba awọn ọmọ Moro laaye lati jokoo ṣe idanwo igbaniwọle sileewe girama lẹyin ti wọn ba jade ileewe alakọọbẹrẹ.

Eyi lo ni o jẹ ọna lati maa tẹ awọn ara agbegbe naa ri, ki wọn ma baa gberi tabi tayọ.

Bakan naa ẹwẹ, Dokita Reuben Kẹhinde Akano ni asiko ti to lati ṣe atunṣe gbogbo awọn ohun to lodi ti Ilọrin ti n ṣe fun awọn ara Moro tipẹ.

Aṣiwaju ilu Afọn Alhaji M.B Baako, ni Ilọrin yii kan naa lo ta ko idasilẹ ijọba ibilẹ Moro ati Asa lọdun 1976, ṣugbọn ijọba ologun to wa nipo nigba naa lo ni dandan, o gbọdọ wa si imuṣẹ.

 

Leave a Reply