Faith Adebọla
Awọn akẹkọọ okoolelọọọdunrun o din mẹta (317) tawọn janduku agbebọn ji gbe loru ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ti dẹni ominira bayii, wọn ti tu wọn silẹ lẹyin ọjọ mẹta ninu igbo oju-ọlọmọ-o-to-o.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọsan ọjọ Aiku, Sannde yii, ni wọn yọnda awọn ọmọbinrin ọhun nigbekun awọn agbebọn naa, ẹsẹ ni wọn ni wọn fi rin de aafin Ẹmia ilu Anka, ibẹ ni wọn ṣi wa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ki wọn too waa fi mọto ko wọn lọ si ọfiisi gomina ipinlẹ Zamfara, ni Gusua, olu-ilu ipinlẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, afẹmọju ọjọ Ẹti, Furaidee yii, niroyin gbode kan pe wọn ti ji awọn akẹkọọ-binrin to le lọọọdunrun gbe ninu ilegbee (hostel) wọn to wa ninu ọgba ileewe ijọba Government Secondary School, to wa lagbegbe Jangebe, nipinlẹ naa.
Ọjọ meje ṣaaju eyi lawọn agbebọn kan lọọ ji awọn ọmọleewe ati tiṣa bii mejidinlogoji gbe niluu Kagara, nipinlẹ Niger, wọn foju wọn ri mabo ki wọn too tu wọn silẹ lọjọ Abamẹta, Satide yii, lẹyin ọjọ mẹsan-an.