Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun oloro nipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Saka Hassan, lẹyin ti wọn ka ori eeyan meji mọ inu ọkọ rẹ.
Awakọ ọhun lọwọ tẹ loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọgbẹni Haruna Gagara to jẹ ọga agba fun ajọ naa nipinlẹ Ondo pe lasiko ti awọn oṣiṣẹ wọn n ṣayẹwo awọn ọkọ loju ọna ọhun ni wọn rí ori eeyan naa (ọkan ti ọkunrin ti ekeji si jẹ ti obinrin) ninu paali kan to ko wọn pamọ si ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti nọmba rẹ jẹ KOGI: LKJ 135 BF.
Ninu alaye diẹ ti afurasi ọhun ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n ṣafihan rẹ, o ni o ti to bii ọdun mẹẹẹdogun toun ti n fi ọkọ na ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, si Okenne, nipinlẹ Kogi.
O ni ọkunrin kan lo gbe ẹru yii sinu ọkọ oun lasiko ti oun n loodu lọwọ ninu gareeji ni Okenne, to si ni ki oun gbe e fun ẹnikan ti oun ba ti de Akurẹ.
Hassan ni oun ko mọ ẹnikẹni ninu awọn mejeeji, o ni nọmba foonu wọn nikan loun ni lọwọ.
Tee-Leo Ikoro ni wọn ti fa afurasi ọhun le ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lọwọ lati ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Ni kete ti iwadii ọhun ba pari lo ni wọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.