Akeredolu tu ẹgbẹ awakọ ka nipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Rotimi Akeredolu ti pasẹ titu ẹgbẹ awakọ mejeeji to wa nipinlẹ Ondo ka lori ẹsun pe wọn n gbe igbesẹ to n pa awọn araalu lara.

Akeredolu ni kawọn adari ẹgbẹ ọhun, Jacob Adebọ (Idajọ) to jẹ alaga ẹgbẹ NURTW, ati Ọgbẹni Bọlarinwa, alaga RTEAN tawọn eeyan tun mọ si Roodu tete kẹru wọn kuro ninu gbogbo gareeji to wa nipinlẹ Ondo lẹyẹ-o-ṣọka.

Oludamọran fun gomina lori akanṣe iṣẹ, Dokita Doyin Ọdẹbọwale, to paṣẹ ọhun lorukọ gomina ni ko sẹni ti wọn ran niṣẹ lati maa gbowo ori lọwọ awọn eeyan ninu gareeji lorukọ ijọba.

O ni ijọba ko ni i faaye gba ọkan-o-jọkan iwa ti ko bofin mu ti wọn n hu ninu awọn ibudokọ wọnyi nitori pe ko sowo ti wọn  n ko fun ijọba ipinlẹ Ondo gẹgẹ bii ahesọ tawọn eeyan kan n gbe kiri.

Adebọwale tun pasẹ fawọn awakọ taksi lati da owo ọkọ wọn pada si aadọta naira ti wọn n gbero tẹlẹ dipo ọgọrun-un naira ti wọn n gbe e bayii.

Lati bii osu meji sẹyin lawọn eeyan ti n ta ko ijọba lori afikun ẹẹdẹgbẹta naira ti wọn fi kun owo tikẹẹti ti wọn n ja fawọn awakọ ero nipinlẹ Ondo, eyi to mu kawọn onitaksi gbe owo ọkọ wọn kuro ni ẹẹdẹgbẹta naira lọ si ọgọrun-un naira.

 

Leave a Reply