Bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe ye, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yorùbá, Iba Gani Adams, Oloye Sunday Adeyẹmọ atawọn ọmọ ẹgbẹ OPC yoo jade lati ṣewọde ta ko jijẹ maaluu nilẹ Yoruba.
Ninu ikede ti wọn ṣe sinu iwe iroyin kan ni Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho ati Iba Gani ti sọrọ yii pẹlu ajọṣepọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, labẹ akoso Ọmọoba Ṣẹgun Ọsinbọtẹ, wọn si ti ya ọjọ kan sọtọ lati fi ṣewọde.
Wọn ni awọn gbe igbesẹ yii lati fẹhonu han lori bi ẹgbẹ awọn to n ta maaluu atawọn ohun jijẹ loke ọya ṣe paṣẹ fawọn eeyan wọn ki wọn ma ṣe ko ounjẹ ati maaluu wa si ilẹ Yorùbá atawon ibomi-in lagbegbe apa Guusu orilẹ ede yii mọ.
Ni bayii, o ti di ọjọ kẹrin ti ẹgbẹ awọn olokoowo ẹran maaluu ti paṣẹ ọhun.
Igbesẹ awọn Hausa yii ko sai ba ibinu awọn eeyan orilẹ ede yii pade nitori kaakiri ori ikanni ayélujára lawọn èèyàn ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọ̀hún.
Ẹgbẹ awọn olounjẹ ati maaluu nilẹ Hausa sọ pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, niluu Abuja ti pe awọn lori idi ti awọn ṣe gbe ìgbésẹ ọhun.
Akọwe ẹgbẹ naa, Ahmed Alaramma, sọ pe titi di asiko yii ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Mohammed Tahir, ṣi wa lọdọ awọn DSS.
Tẹ o ba gbagbe, awọn eeyan yìí naa lo n béèrè ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu lọwọ ijọba àpapọ gẹgẹ bíi owo gba ma binu pe wọn pa awọn eeyan awọn lasiko rogbodiyan to waye ni Shasha.