Faith Adebọla, Eko
Ọba ilu Eko, Rilwan Arẹmu Akiolu, ti ṣalaye pe miliọnu meji owo dọla ($2million) ati milọnu mẹtadinlogun naira (N17million) ni wọn ko lọ laafin oun ni Iga Iduganran, nisalẹ Eko, lasiko iwọde ta ko SARS to waye lọdun to kọja.
Yatọ si towo, ọba naa lawọn janduku tun ji ọpa aṣẹ oun gbe lọ, atawọn dukia mi-in to wa ninu aafin naa.
Akiolu sọrọ yii nigba to n sọrọ nibi ṣiṣi gbọngan igbalode Glover Hall Memorial, tijọba kọ si Opopona Broad, Marina, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.
O lawọn nnkan toun padanu lasiko ti wọn ṣe akọlu si aafin oun pọ gidi, oun si fẹ ki ijọba apapọ ṣeranwọ fun ipinlẹ Eko lati ṣe atunkọ awọn nnkan ti wọn bajẹ lasiko yanpọnyanrin ọhun.
“Ma a fọwọ si ohunkohun to maa mu itẹsiwaju ba ilu Eko. Mo ti parọwa si ijọba apapọ lati ran ilu Eko lọwọ latari awọn nnkan ta a padanu lasiko wahala yẹn. Iṣẹlẹ to waye logunjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja yẹn, baayan lọkan jẹ gidi. Ohun ta a padanu nipinlẹ Eko kuro ni wasa.
“Ọpọ ile ni wọn dana sun, titi kan awọn mọto ti a fi n pawo wọle. Mo le sọ ọ ni gbangba bayii pe miliọnu meji owo dọla ati miliọnu mẹtadinlogun owo naira ni wọn ji laafin mi, yatọ si ti ọpa aṣẹ atawọn dukia mi-in ti wọn ko lọ.
“Awọn to huwa buruku yii iba ma ṣe bẹẹ ka ni wọn mọ itumọ ohun ti wọn ṣe yẹn ni. Ṣugbọn gẹgẹ bii baba ti mọ jẹ, mi o ni i fi wọn gegun-un” Bayii ni Ọba Akiolu wi.