Nitori tiyẹn tọ sile, Aisha fina jo ọmọ ọkọ ẹ loju-ara

Ọjọ kẹrinla, oṣu keji, to kọja, ni obinrin yii, Aisha Abdullahi Gaide, fi ina jo ọmọ ọkọ ẹ, Zahra Abdullahi, ti ko ju ọmọ ọdun mẹjọ lọ loju ara, ṣugbọn ajọ kan to n ri si iwa ika bii eyi ti lawọn yoo ba a mu nnkan nilẹ, wọn ni yoo jiya ohun to ṣe fọmọ ọdun mẹjọ naa gidi.

Ajọ kan ti wọn n pe ni State Action Committee On Gender-Based Violence( SGVB) lo fa Aisha le awọn ọlọpaa teṣan Bauchi ti iṣẹlẹ yii ti waye lọwọ.

Niṣe ni wọn ni Zahra tọ si aṣọ to wọ nigba to sun, eyi si bi iyawo baba ẹ ninu ( iya Zahra ti kọ baba ẹ ṣilẹ.) Ibinu naa ni wọn lo mu Aisha fa waya ina yọ, o si bẹrẹ si i fi lu ọmọ ọdun mẹjọ naa bii ko ku.

Lẹyin to lu u tan ni wọn lo tun mu iṣana, lo ba ṣa a, o si fi jo ọmọ naa loju ara to jẹ niṣe ni gbogbo oju abẹ naa bo torotoro.

Nibi ti Zahra ti n sunkun kiri pẹlu inira lawọn eeyan ti gba ọrọ rẹ ro, to fi de etiigbọ ajọ to fẹẹ ran an lọwọ yii, ti wọn fi mu iyawo baba ẹ si teṣan, to si ti bẹrẹ si i fimu kata ofin.

Leave a Reply