Wọn wole ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa l’Abuja

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

 

Bi eeyan ba dé ibi ti ile ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa niluu Abuja wa bayii, tọ̀hún yóò ro pe oun ṣìnà ni, tabi pe ojú àlá loun wa pẹlu bi wọn ṣe wo ile nla naa lulẹ, to sì ti ku kìkìdá èérún okuta patapata bayii.

Lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn wólé ọ́hún tó wà laduugbo Asokoro, niluu Abuja, ni ibamu pẹlu àṣẹ Gomina ipinlẹ Ọyọ funra rẹ̀, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe akọwe iroyin gomina ṣe fìdí ẹ mulẹ, nitori pe Ẹnjinnia Makinde fẹẹ tun ile ọhun kọ lo ṣe pàṣẹ fún ileeṣẹ àkọlé pé ki wo wọn wo o lulẹ, ki wọn sí tun un kọ.

O ni “ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹẹ ṣàtúnṣe sí ile yẹn lati jẹ ko bá igbà mu ni. Ìdí nìyẹn tí wọn ṣe wo abala kan ninu ẹ nitori inú yẹn ko sí ní ìbámu pẹlú irufẹ iṣẹ atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe sile yẹn”.

O ni ileeṣẹ ti wọn gbé iṣẹ fún láti tún ile ọhún kọ naa lo wo o, ati pe ni kete ti wọn ba ti palẹ awọn eerun àlàpà naa mọ tan ni wọn yóò bẹrẹ sí í tún un kọ ti ile naa yóò sì di awoṣifila fún gbogbo ẹni tó bá rí i.

Leave a Reply