Stephen Ajagbe, Ilorin
Ko daju pe wahala to n ṣẹlẹ laarin ijọba atawọn ileewe tawọn ẹlẹsin Krisitẹni da silẹ ni Kwara lori ọrọ lilo ibori fawọn akẹkọọ-binrin ṣetan lati dopin rara, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, tun ni awọn alakooso ijọ Evangelical Church Winning All (ECWA), nipinlẹ Kwara, sọ pe awọn ko ni i gba kijọba kan ibori mọ awọn lori.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Alaga ijọ ECWA, niluu Ilọrin, Ẹni-Ọwọ John Owoẹyẹ, ran ijọba leti pe niwọngba tijọba ko ti le gbe olukọ imọ bibeli lọ sawọn ileewe Musulumi, ti wọn ko si gba ipejọpọ awọn ọmọlẹyin Kristi, Fellowship of Christian Students (FCS) lawọn ileewe naa, ijọba ko lẹtọọ rara lati kan hijaabu nipa fawọn akẹkọọ tabi kan an le awọn lori ni tipa.
Owoẹyẹ ni igbesẹ tijọba fẹẹ gbe lati gbe hijaabu jade ti gbogbo ileewe; tijọba ati tajọ krisitẹni, yoo maa lo, ko le fẹsẹ mulẹ laelae, nitori pe gbogbo ọna lawọn yoo fi daabo bo igbagbọ awọn, awọn ko si ni i gba ẹnikẹni laaye lati tẹ ẹtọ awọn loju mọlẹ.
O ṣalaye pe awọn baba igbagbọ to mu ẹsin Krisitẹni wa sorilẹ-ede Naijiria lo gbe awọn ileewe ECWA kalẹ lati fifẹ han si araalu ati lati pese eto ẹkọ to ye kooro, lai ka ẹya tabi ẹsin araalu si.
Awọn adari ECWA naa n beere fun idapada awọn ileewe wọn, nitori pe ninu adehun to wa laarin awọn alaṣẹ ileewe to jẹ ti Krisitẹni ati ijọba, eyi ti wọn tọwọ bọ lọdun 1974, ko si nibẹ pe ijọba maa gba ileewe awọn patapata.
Wọn ni ninu oogun awọn lawọn fi n ṣe atunṣe awọn ileewa naa, ko si si bijọba ṣe le gba ogun awọn lọwọ awọn nipa kikan ofin kan le awọn lori.
Owoẹyẹ ni ojulowo ọmọ Kwara lawọn Krisitẹni, wọn ni ẹtọ kan naa tawọn Musulumi ni labẹ ofin. O ni igbesẹ tijọba gbe lori ọrọ hijaabu yii ti fi han pe wọn fẹẹ gbe ẹsin kan ga ju ikeji lọ, ko si le ṣee ṣe laelae.