Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina Rotimi Akeredolu ti ni o di dandan fun gbogbo awọn ileewe alakọọbẹrẹ, girama ati ile-ẹkọ giga to wa nipinlẹ Ondo pẹlu ileesẹ ijọba lati maa kọrin adakọ to jẹ ti ibilẹ Oduduwa tuntun tijọba ṣe ifilọlẹ rẹ lọsẹ to kọja.
Asẹ yii lo waye ninu atẹjade kan ti Akọwe agba fun ileeṣẹ to n ri ṣeto ẹkọ ati imọ sayẹnsi nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Akin Asaniyan, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
O ni aṣẹ tuntun naa ti bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun ta a wa yii, ati pe ileewe ijọba tabi ti aladaani to ba kọ lati tẹle aṣẹ naa yoo ri ibinu ijọba.
Inu ipade aṣekẹyin tí Gomina Akeredolu ṣe pẹlu awọn igbimọ rẹ ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni wọn ti fẹnu ko lori ifilọlẹ akanṣe orin adakọ naa.
Awọn olorin ibilẹ ileeṣẹ asa ati irinajo afẹ ipinlẹ Ondo ni wọn ṣagbekalẹ orin ọhun, ti wọn si ṣafihan rẹ fun gomina ati awọn ọmọ igbimọ iṣakoso rẹ lọjọ naa.
Orin ọhun ree
Iṣẹ wa fun ilẹ wa
Fun ilẹ ibi wa
Ka gbe e ga
Ka gbe e ga
Ká gbe e ga fun aye ri.
Igbagbọ wa ni pe
Ba ti bẹru la bọmọ
Ka ṣiṣẹ
Ka ṣiṣẹ
Ka ṣiṣẹ ka jọ la
Iṣọkan ati ominira
Ni kẹ jẹ ka maa lepa
Tẹsiwaju fọpọ ire
Ati ohun to dara
Ọmọ Odua dide
Bọ di ipo ẹtọ rẹ
Iwọ ni imọlẹ
Ìwọ ni imọlẹ
Gbogbo Adulawọ