Ọlawale Ajao, Ibadan
O fi han pe nnkan ko lọ deede ninu ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic party, PDP ni ipinlẹ Ọyọ pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣe binu ya bo ọfiisi gomina ipinlẹ naa fún ifẹhonu han, wọn lawọn alagbara inu ẹgbẹ naa n fọwọ ọla gba awọn loju.
Awọn olufẹhonu han ọhun ti wọn wa lati ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ọyọ ni wọn fi aidunnu wọn han si bí awọn adari ẹgbẹ wọn nijọba ibilẹ naa ṣe fi tipatipa yan awọn ti yoo dije dupo lorukọ ẹgbẹ naa le awọn lori lasiko idibo ijọba ibilẹ to maa waye ninu oṣu karun-un, ọdun 2021 yii.
Oríṣìíríṣìí orin ọtẹ lawọn eeyan yii n kọ pẹlu ọpọlọpọ paali ti wọn kọ onírúurú akọle sí lọwọ wọn.
Lara ohun ti wọn kọ sínú àwọn paali ifẹhonuhan ọhún ni “a kò fẹ oludije tí wọn yóò fi tulaasi yan le wa lori nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ọyọ”. “Ibo abẹ́lé la máa fi fa oludije kalẹ nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ọyọ” “Ẹyin adari PDP ipinlẹ Ọyọ, ẹ́ ranti ohun tó pa ẹgbẹ PDP lọjọsi” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn nigba to n dahun ibeere awọn oniroyin lori iṣẹlẹ yii, Ẹnjinnia Akeem Ọlatunji ti í ṣe agbẹnusọ fẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọyọ sọ pe awijare awọn olufẹhonu han naa ko fẹsẹ mulẹ nitori ko sí nnkan to jọ pe wọn n fipa yan ẹnikẹni le gbogbo ọmọ ẹgbẹ lori nibikibi ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Àmọ́ ṣaa, o ni oun ati alaga ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ yii, Alhaji Kumi Mustapha, ti ba awọn olufẹhonu han naa sọrọ, ohun gbogbo si ti n lọ lalaafia bo ṣe yẹ.