Faith Adebọla
Wọn ti fẹsun kan awọn alapata ọmọ Yoruba kan lagbegbe Ibarapa pe awọn ni wọn n ṣe agbodegba fawọn Fulani darandaran lati ṣe awọn agbẹ ni ṣuta lagbegbe Ibarapa, wọn ni tori maaluu ti wọn n ra lọwọ awọn Fulani naa ni wọn ṣe n ṣe bẹẹ.
Olori ẹgbẹ Odua Peoples Congress, (OPC) nilẹ Ibarapa lapapọ, Kọmureedi Ọlanrewaju Ogedengbe, lo sọrọ yii f’ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nipa wahala awọn Fulani pẹlu awọn agbẹ lagbegbe ọhun, ati ibi ti nnkan de duro.
O ni niṣe lawọn Fulani darandaran yii n mura lati le awọn agbẹ kuro loko, ati lori ilẹ wọn, wọn o fẹ kẹnikẹni le kọja sọna oko mọ.
“Ṣẹ ẹ ri gbogbo ohun ti wọn fẹẹ ṣe, wọn fẹẹ le awọn agbẹ kuro loko patapata nilẹ kaaarọ-oo-jiire ni, ko si yẹ ko ri bẹẹ, ko yẹ ko jẹ bẹẹ, ki alejo tun waa maa sọ fonile pe o ku ibi ti yoo gba.
“Ṣugbọn ọpọlọpọ wa naa ta a jọ jẹ iran Yoruba, alabọde, agbẹyin-bẹbọjẹ wa laarin wa, to jẹ pe bi a ba ti n sọrọ nibi kan, a o ni i ti i kuro nibẹ ti wọn fi maa lọọ ṣofofo ẹ fawọn araabi.
“Lara awọn to n huwa agbẹyin-bẹbọjẹ yii, awọn alapata kan to n ra ẹran lọwọ awọn Fulani yii ni. Awọn ni wọn n ṣaroye pe ti a ba le awọn Fulani lọ, nibo lawọn ti maa maa ri ẹran ra, a si n jẹ ko ye wọn pe ki agbado too d’aye, kinni kan ni adiẹ n jẹ.
“Koda, awọn agbẹ mi-in naa huwa aidaa fun wa. Awọn kan lara wọn ti wọn ti janfaani awọn Fulani yii sẹyin, to jẹ bi maaluu wọn ba ṣaisan tabi to ku lojiji, awọn agbẹ bẹẹ ni wọn n fi ta lọrẹ, lara wọn wa ti iwadii wa fihan pe wọn n ṣe agbodegba fawọn Fulani.
“Niṣe niru awọn eeyan yii n kọdi sita, ti wọn n tọ sile, a si ti fẹjọ wọn sun Aarẹ-ọna-kakanfo, Iba Gani Adams, wọn si ti lawọn maa gbe igbesẹ nipa wọn, a si mọ pe Ọlọrun wa lẹyin wa.”