Faith Adebọla
Akolo ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Atiba, nipinlẹ Ọyọ, lawọn Hausa mẹrindinlogun ati ibọn mejidinlogun ti wọn gba lọwọ wọn wa bayii, awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun lo mu wọn lagbegbe Ori-Awo, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, inu ọkọ akẹru nla kan ni wọn lawọn Hausa naa kora wọn si, ti wọn si tọju awọn ibọn wọn sabẹ awọn apo ṣaka ti wọn di ẹru le lori ninu mọto naa.
Wọn ni nigba ti wọn bi wọn leere ibi ti wọn ti n bọ ati ibi ti wọn n lọ, awọn Hausa naa fesi pe lati ipinlẹ Sokoto, lapa Oke-Ọya lọhun-un, lawọn ti gbera, wọn ni agbegbe Igbo Nla, nipinlẹ Ọyọ lawọn n lọ, awọn kan lara wọn si ni agbegbe National Park, to wa niluu Ọyọ lawọn n lọ.
Amọ wọn ni wọn o r’alaye to nilaari kan ṣe nigba ti wọn bi wọn leere idi ti wọn fi n ko ibọn kiri nigba ti wọn ki i ṣe ọlọdẹ tabi eleto aabo, eyi lo mu kawọn Amọtẹkun fura pe niṣe ni wọn fẹẹ lọọ fibọn naa ṣe ṣuta.
Wọn ni ọkan lara awọn Hausa naa sọrọ lede Hausa pe tori ija to waye lọja Ṣaṣa lọjọsi lawọn ṣe wa, awọn fẹẹ maa fi ibọn naa daabo bo ara awọn ni.
Yatọ si ibọn, wọn tun ba oriṣiiriṣii oogun abẹnugọngọ, igbadii, tira, ọbẹ aṣooro atawọn nnkan ija mi-in lọwọ wọn.
Ṣa, ikọ Amọtẹkun ti ko awọn afurasi ọdaran naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa fun iwadii, wọn si ti ko awọn ibọn ti wọn gba lọwọ wọn naa fawọn ọlọpaa Atiba.