Faith Adebọla
Titi di asiko yii lawọn eeyan ṣi n fi aidunnu wọn han si erongba ati imọran ti agba oloṣelu ati adari ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nni, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, gbe jade lori wahala to n fojoojumọ waye laarin awọn agbẹ ati awọn Fulani darandaran kaakiri orilẹ-ede yii, ọpọ lo n sọ pe imọran naa lọwọ kan abosi ninu, awọn mi-in si woye pe ọrọ naa ko le yanju iṣoro to wa nilẹ yii, niṣe lo maa da kun un.
Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ni Tinubu fi erongba rẹ han ninu atẹjade kan to kọ lati da si ọrọ to n ja ranyin ọhun, ati lati gba ijọba nimọran lori ọna abayọ. Ọkan gboogi ninu imọran ti oloṣelu naa gba ijọba atawọn araalu ni pe ki wọn bẹrẹ si i yọnda awọn ilẹ wọn ti wọn ko ti i lo, tabi ti wọn ko lo mọ fawọn darandaran onimaaluu kaakiri orileede yii, ki wọn le maa fi ko awọn ibudo ijẹko maaluu si. O ni eyi lo le mu ki iṣoro awọn Fulani darandaran lọ sokun igbagbe, ki alaafia si wa laarin awọn darandaran ati awọn onilẹ ti wọn gba wọn lalejo, ti iṣoro a-n-fi-maaluu jẹko, a-n-fi-maaluu ba oko oloko jẹ, yoo dohun itan.
Bi atejade naa ṣe jade sori atẹ ayelujara lo ti bẹrẹ si i lọ yika, bẹẹ lawọn eeyan ti n fi ero ọkan wọn han, ti wọn n fesi si ọrọ ti Asiwaju sọ, o ṣetan, ọpọ lo ti n ri si didakẹ ti agba oṣelu ilu Eko naa dakẹ latigba ti wahala awọn darandaran naa ti bẹrẹ, ọpọ awọn to si sọrọ lo kọminu si ọrọ ati amọran Tinubu yii.
Ọkan ninu awọn to kọkọ sọrọ ni agba ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, o ni ijọba o le fipa mu ẹnikẹni tabi awọn ijọba ipinlẹ ati ibilẹ lati yọnda awọn ilẹ wọn fawọn onimaaluu tori ati kọ ibudo ijẹko, o ni iru imọran bẹẹ maa da wahala mi-in silẹ ni.
Adebanjọ ni ko sohun to buru ti ẹnikan tabi ijọba kan ba fẹẹ yọnda ilẹ rẹ fawọn darandaran, ṣugbọn ko si ọrọ tulaasi ninu rẹ, wọn ko si le ṣofin kan to maa sọ ọ di ọran-anyan fẹnikẹni, tori awọn eeyan le pinnu boya o wu awọn lati ni ibudo ijẹko lagbegbe awọn tabi ko wu wọn.
Ninu atẹjade kan ni Adebanjọ ti sọrọ naa lọjọ Satide, o tẹsiwaju pe ko yẹ ki Tinubu duro lori ọrọ awọn darandaran nikan, o lo yẹ ko sọrọ lori iṣoro aabo to mẹhẹ, ati bawọn gomina ko ṣe laṣẹ kan dan-indan-in lori awọn ọlọpaa, eyi to n mu ki wahala ọrọ aabo yii tubọ fẹju lasiko yii.
Bi Afẹnifẹre ṣe n sọ tirẹ, bẹẹ ni ẹgbẹ awọn agba Yoruba, Yoruba Council of Elders (YCE) naa sọ. Akọwe agba ẹgbẹ naa, Dokita Kunle Ajibade, sọ pe awọn o fara mọ ọrọ ti Tinubu sọ yii rara, o ni bo ṣe wa ni liki lo yẹ ko wa ni gbanja, tori okoowo ara-ẹni ni ọsin maaluu jẹ fawọn darandaran, bẹẹ lawọn eeyan ti ki i ṣe darandaran naa ni okoowo ara-ẹni tiwọn, aparo kan ko si ga ju ọkan lọ.
O ni tijọba ba bẹrẹ si i ṣeto ilẹ fawọn darandaran lati kọ ibudo ijẹko wọn kaakiri ilu ati ipinlẹ, bẹẹ lo yẹ kijọba ṣeto fawọn to n sin adiẹ, awọn to n sin ẹlẹdẹ, awọn to n ṣe iṣẹ agbẹ ohun ọsin loriṣiiriṣii kaakiri awọn ipinlẹ ati igberiko, aijẹ bẹẹ, iṣoro mi-in ni iwa ojuṣaaju bẹẹ yoo da silẹ kaakiri agbegbe, eyi si le mu kawọn eeyan bẹrẹ si i gbeja ko awọn onimaaluu lagbegbe wọn.
“Ijọba gbọdọ dẹkun iwa fifọwọ ra awọn onimaaluu lori. Ọwọ ti wọn ba fi mu awọn onimaaluu ni wọn gbọdọ fi mu awọn yooku. Ki nidii ti wọn fi gbọdọ maa lo ilẹ araalu fun awọn darandaran lati kọ ibudo ijẹko wọn. Niṣe ni ki wọn jẹ ki awọn darandaran tọ ọna tawọn olohun ọsin yooku n tọ, ki wọn wa ilẹ wọn funra wọn, ki wọn ra a tabi rẹnti ẹ, ki wọn tọwọ bọwe adehun, ki wọn sanwo to yẹ, ki wọn si maa ṣe okoowo maaluu wọn lai pa ọmọlakeji lara tabi kọja ofin.
“Awọn araalu lo ni ilẹ ki i ṣe ijọba. Ijọba wulẹ n ba wọn bojuto o ni, ohun tawọn araalu ba fẹ ni ṣiṣe. Ti awọn araalu o ba fẹ kawọn onimaaluu wa lagbegbe awọn, ijọba kijọba to ba yọnda ilẹ ilu fun wọn wulẹ n kọ lẹta si ibinu araalu ni, wahala si nijọba naa n fa lẹsẹ yẹn.”
Yatọ sawọn eekan eekan to ti fesi ta ko aba ti Tinubu mu wa yii, ṣọṣọ ni atẹ ayelujara kun fun oniruuru ọrọ ati eebu tawọn eeyan n fi ṣọwọ si agba oloṣelu yii, wọn lawọn ti n porungbẹ ọrọ ati ero rẹ lori wahala to wa niluu ju bo ṣe waa ja awọn kulẹ pẹlu imọran olojuṣaaju to gba wọn yii. Wọn niṣe ni Tinubu fari apa kan da ekeji si, ọpọ lo si sọ pe afaimọ ko ma jẹ tori erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023 ni baba naa ko fi le sọrọ sibi tọrọ wa.
Wọn ni awọn o mọ idi ti Tinubu fi duro di akoko yii ko too sọrọ, wọn ni agba to ba fẹ ki ilu toro ki i dakẹ lasiko to yẹ ko sọrọ, tori kekere la a ti pẹkan Iroko, to ba dagba tan, ẹbọ ni yoo maa gba, leyii to tumọ si pe ki iṣoro too fẹju lo yẹ keeyan ti wa ojuutu si i, kọrọ naa maa baa di kudẹti mọ-ọnyan lọwọ, wọn nibi tọrọ de duro bayii ti kọja iru amọran ti Tinubu mu wa yii. Lakọọkọ, wọn niwa abeṣe tawọn darandaran naa n hu ti kọja fifi maaluu jẹ oko, tori awọn naa ni wọn fẹsun kan pe wọn n yinbọn pa awọn agbẹ sinu oko wọn, ti wọn n jiiyan gbe lati gba owo nla lọwọ awọn mọlẹbi ẹni ti wọn ba ji gbe, ti wọn si n fipa ba awọn obinrin lo pọ, yatọ sawọn iwa aburu mi-in ti wọn ni wọn n hu.
Ohun mi-in tawọn araalu to fesi sọrọ Tinubu yii tun n sọ ni pe awọn darandaran ta a n sọrọ wọn yii, ọpọ wọn ki i ṣe ọmọ orileede yii, wọn lawọn orileede ilẹ Afrika mi-in bii Nijee, Mali, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti wa, tori naa, yoo ṣoro keeyan too wa lati orileede mi-in lai gba iwe-aṣẹ igbeluu, ko waa jẹ ijọba ibi to foru boju wọle lo maa maa ṣe kuku-kẹkẹ kikọ ibudo ijẹko fun awọn nnkan ọsin onitọhun.
Ero mi-in tawọn eeyan tun sọ ta ko amọran ti Tinubu mu wa yii ni pe iwa tawọn onimaaluu hu lẹnu ọjọ mẹta yii, ti wọn lawọn o ni i ko ounjẹ wa sawọn agbegbe ilẹ Naijiria to ku, awọn o si ni i ta maaluu fun wọn ti fi ero ọkan buruku ti wọn ni han. Wọn ni iwa naa fihan pe ṣe ni awọn darandaran ọhun n ri ara wọn bii ọga ati alagbara lori awọn eeyan agbegbe to ku. Wọn ni bi awọn darandaran onimaaluu ba fi le ṣe huwa bi wọn ṣe ṣe yii, wọn ni aṣẹ-ma-ṣee-bawi ni wọn maa sọ ara wọn da ti wọn ba faaye gba wọn lawọn agbegbe kaakiri.
Ṣaaju, ninu ọrọ ti Tinubu sọ lo ti loun ri i pe ọrọ awọn darandaran pẹlu awọn agbẹ ti di eyi ti awọn kan n foju ẹlẹyamẹya wo, o ni eyi lewu gidi fun orileede wa, tori ti iṣoro ẹlẹyamẹya ba burẹkẹ, ina nla ti ko ni i ṣee pa bọrọ ni yoo da.
Lara awọn aba ati igbesẹ ti Bọla ni kijọba apapọ gbe ni pe ki wọn pepade nla, ipade ti yoo ni awọn onṣejọba, awọn gomina, awọn ọba alaye, awọn agbofinro, awọn olori ẹsin, awọn aṣoju ẹgbẹ onimaaluu ati awọn agbẹ, atawọn mi-in bẹẹ ninu, o ni ki gbogbo wọn jokoo yi tabili po, ki apero ati amọran gidi le waye lori ọna to daa ju lọ lati yanju iṣoro ọhun.
O ni tipade naa ba pari, kawọn gomina ipinlẹ kọọkan lọọ ṣe agbekalẹ awọn igbimọ bii iru eyi lawọn ipinlẹ wọn, ki wọn si ṣamulo awọn amọran ti wọn fẹnu ko si lapapọ.
Tinubu ni asiko ti to funjọba lati ṣamulo imọ ẹrọ igbalode, awọn ọna iwadii ati iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ igbalode, to maa jẹ ki olobo tete ta wọn ti awọn kan ba fẹẹ ṣe ṣuta laduugbo kan.
O tun rọ ijọba lati pese ọna to dara, omi to mọ ati awọn nnkan amayedẹrun to maa mu ki igbe aye awọn to wa ninu oko, ni awọn igberiko ati ilu nla rọrun.