Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji lo padanu ẹmi wọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ninu ija to bẹ silẹ laarin wọn lagbegbe Aduralere, niluu Ilọrin.
ALAROYE gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ meji ọtọọtọ; Aiye ati Ẹiyẹ lo jọ gbena woju ara wọn, leyii to fa iku airọtẹlẹ awọn meji naa, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun ti wọn n fa mọ ara wọn lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ọwọ idaji lo ṣẹlẹ.
O ni awọn ti n gbiyanju lati ri awọn to ṣiṣẹ ibi naa mu, laipẹ nigbagbọ si wa pe ọwọ maa tẹ wọn.
Ọkasanmi fọkan araalu paapaa ju lọ awọn ara agbegbe naa pe alaafia ti wa nibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
O ni ọga ọlọpaa, Muhammed Bagega, ti paṣẹ fawọn alakooso agbegbe, DPO, lati bẹrẹ si i tọ gbogbo ipinlẹ Kwara ka lati ri i pe ọwọ tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati ọdaran to n yọ araalu lẹnu yii.