Stephen Ajagbe, Ilorin
Olukọ ileewe giga kan to wa niluu Ọffa, Kwara State College of Health Technology, Abdullahi Ọpaṣhọla, ati ọmọ iya meji ti wọn jẹ ibeji, Taiye-Kẹhinde Adebayọ, ni wọn ti dero ẹwọn bayii fẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara tawọn eeyan mọ si ‘Yahoo-Yahoo’.
Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu tile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Kwara lo paṣẹ pe ki Ọpaṣhọla lọọ ṣẹwọn oṣu mẹrin, o si sọ awọn ibeji naa sẹwọn oṣu mẹfa.
Ajọ EFCC lo wọ awọn afurasi mẹtẹẹta lọ sile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibi tile-ẹjọ ti gbe idajọ rẹ kalẹ.
Awọn olujẹjọ mẹtẹẹta gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan wọn.
Ọpaṣhọla ni wọn lo n lo ayederu orukọ; Devin Snow, pẹlu foto obinrin alawọ funfun, lati fi lu oyinbo kan, Eugene Myvett, ni jibiti igba dọla, $200 USD.
Ni ti Taiye Adebayọ, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe, laarin oṣu kin-in-ni, ọdun 2020, o lu oyinbo kan, Gary Brenton, to pade lori ikanni ibanidọrẹẹ TWOO, ni jibiti ẹẹdẹgbẹta din mẹwaa dọla, $490.
Bẹẹ naa lẹsun ti wọn fi kan Kẹhinde Adebayọ, ori ikanni TWOO kan naa lo ti pade Gary Brenton, to si lu u ni jibiti irinwo dọla, $400 USD, lẹyin to fi ifẹ ẹtan tan an, to si pe ara rẹ ni obinrin fun iyẹn.
Agbẹjọro EFCC, Andrew Akoja, ko awọn ẹri to daju silẹ, o si pe awọn ẹlẹri meji; Paul Kera ati Emezie Dominic, lati jẹrii lori ẹsun naa.
Adajọ Akinpẹlu ni ki olukọ ileewe giga naa, Ọpaṣhọla, ṣẹwọn tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un le aadọta naira, #150,000.
Bakan naa, Adajọ fun Taiye ati Kẹhinde lanfaani lati sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira lori ẹsun kọọkan ta a fi kan wọn tabi ki wọn lọọ ṣẹwọn. Ẹsun mẹfa ọtọọtọ to da lori jibiti ni EFCC fi kan awọn mejeeji.