Florence Babaṣọla
Adajọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn ọkunrin meji kan; Ishọla Hassan, ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Saka Moshood, ẹni ọdun mejidinlaaadọta, pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun ipaniyan.
Inspẹkitọ Elijah Adeṣina to jẹ agbefọba sọ ni kootu pe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii, lawọn olujẹjọ lọ si abule kan ti wọn n pe ni Oke-Ọra, nitosi Ileefẹ, ti wọn si yinbọn pa Ṣẹgun Awotunde.
Bakan naa ni wọn yinbọn mọ Ọpẹyemi Rabiu lori, ṣugbọn ti Ọlọrun ko iyẹn yọ lọwọ iku ojiji nirọlẹ ọjọ naa. Itan (Thigh) la gbọ pe ibọn ti ba ẹni kẹta ti awọn olujẹjọ doju ibọn kọ, Adesọji Yinka, ileewosan ni wọn si ti doola ẹmi rẹ.
Lara ẹsun ti wọn tun fi kan olujẹjọ, yatọ si pe wọn paayan, ni pe wọn gbiyanju lati paayan, wọn da egbo sara awọn eeyan, wọn si da omi alaafia abule naa ru pẹlu iwa ti wọn hu nibẹ.
Gbogbo awijare awọn olujẹjọ nile-ẹjọ yii danu, Adajọ A. A. Adebayọ sọ pe ki agbefọba mu ẹda iwe ipẹjọ wọn lọ si ẹka to n ri si ọrọ awọn araalu nileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun fun imọran.
Adebayọ paṣẹ pe ki wọn lọọ fi awọn olujẹjọ mejeeji pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi ti igbẹjọ yoo tun fi waye lori ọrọ wọn.