Jide Alabi
Nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni iroyin kan jade pe awọn Fulani meji kan lọọ ka iya to bi ọkunrin ajijagbara nni, Sunday Igboho, mọ ile mama naa to wa niluu Igboho pẹlu erongba ati pa a.
Minisita fun ileeṣẹ ofurufu nilẹ wa, Oloye Fani Kayọde lo sọ ọrọ naa di mimọ. Ọkunrin yii lo gbe e sori ẹrọ ayelujara pe, ‘‘Mo ṣẹṣẹ ba Sunday Igboho sọrọ tan laipẹ yii ni, o si sọ fun mi pe awọn atọhunrinwa Fulani meji ni ọwọ tẹ ni ile mama oun to wa ni Igboho.
‘‘Erongba wọn ti wọn fi wa si ile naa ni lati pa mama naa lara. Ọkan ninu wọn sa lọ, wọn si ri ekeji mu, o ti wa lọdọ awọn ọlọpaa bayii. Awọn ti wọn ran wọn niru iṣe bayii n fi ina ṣere.’’ Fani Kayọde lo sọ bẹẹ.