Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ti iroyin kan ti kari aye, pe Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, sọ pe ki Naijiria wa niṣọkan lo daa, ka ma pin rara, ni awọn eeyan ti n sọko ọrọ ranṣẹ si Kabiyesi. Eyi lo fa a ti ọba alaye naa fi tun alaye rẹ ṣe pe oun ko sọ ohun to jọ bẹẹ rara.
Ninu esi ti Kabiyesi da pada, eyi ti ẹda rẹ tẹ ALAROYE lọwọ, ti Bada Tayeṣe ilẹ Ẹgba, Oloye Zents Kunle Ṣowunmi, fi sita ni wọn ti ṣalaye pe Alake ko tilẹ ba ikọ ẹgbẹ onimọto NRTEAN to waa ṣabẹwo si i laafin rẹ lọjọ naa sọ ohun to jọ bii eyi rara.
Atẹjade naa sọ pe bi Kabiyesi yoo tilẹ sọ ọrọ nla bẹẹ, yoo ni lati ba awọn agba Ẹgba Traditional Council sọrọ na, awọn Ogboni yoo gbọ si i pẹlu, bẹẹ naa si ni awọn alalẹ ti wọn jẹ oriṣa ilẹ Ẹgba naa yoo fọwọ si i.
Fun idi eyi, Ọba Alake ilẹ Ẹgba sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin yii gbọ rara. Ki awọn ọmọ Ẹgba kaakiri aye ma si ṣe tẹle e.
Ṣugbọn ko jọ pe ọrọ naa ta leti awọn eeyan ti wọn ni Kabiyesi ta ko Sunday Igboho. Awọn wọnyi sọ pe ẹri to daju wa pe Alake ṣọ pe ipinya ko le ran Naijiria lọwọ, nitori bii ẹrù lawọn ọmọ Naijiria yoo jẹ nilẹ ajeji ti wọn ba wa lẹyin ipinya, bẹẹ si ni ogun abẹle ni kinni naa yoo jọ.
Awọn epe rabandẹ ti ko ṣee kọ soju ewe iwe iroyin lawọn eeyan pupọ ti n gbe ọba yii ṣẹ lori intanẹẹti, bẹẹ ni awọn mi-in n fẹsun kan an pe owo to gba lọwọ ijọba apapọ ni ko ṣe le sọ otitọ ọrọ. Wọn ni Kabiyesi fẹẹ ta Yoruba fun awọn ẹya to n ṣejọba lọwọ ni.
Ṣe Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan n pe ni Igboho Ooṣa, ti sọ lọsẹ to kọja pe Yoruba ki i ṣe ara Naijiria mọ, to ni ka pinya kuro ni Naijiria nikan lọna abayọ. Ọpọ eeyan lo n sọ ero ọkan wọn lori ọrọ yii, oun naa lo si bi eyi ti wọn ni Alake sọ.
Ọrọ yii ṣi n ja ran-in-ran-in nilẹ, ibi ti yoo yọri si ko ti i ye ẹnikẹni.