Florence Babaṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri bayii pe majele ounjẹ lo ṣeku pa mẹta lara wọn onibaara ti wọn maa n duro lori afara omi to wa ni Oke-Gada, niluu Ẹdẹ.
Aarọ ọjọ Iṣẹ́gun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ahesọ naa n lọ kaakiri pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn kan ti wọn n wa owo ojiji ni wọn fi nnkan sinu ounjẹ ti wọn gbe fun awọn onibaara naa, eleyii to yọri si iku awọn mẹta, ti awọn mẹta mi-in si wa lọsibitu.
Ọrọ naa lagbara debii pe paroparo ni ori gada ti awọn onibaara bii ọgọrun-un ọhun maa n duro si da lọjọ naa, gbogbo awọn Hausa atawọn Yoruba ti wọn maa n ṣagbe nibẹ ni wọn ti fidi mọnu ile wọn.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ọrọ naa ko ni i ṣe pẹlu majele inu ounjẹ rara, bi ko ṣe ti ajakalẹ arun kọlẹra to ṣabẹwo sagbegbe naa.
O ṣalaye pe DPO agọ ọlọpaa to wa l’Ẹdẹ ti ṣabẹwo sọdọ Seriki Hausa niluu naa lori iṣẹlẹ yii, nitori wọn ko fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Ọpalọla sọ pe funra Seriki ọhun lo sọ pe kọlẹra lo fa iṣẹlẹ iku awọn mẹtẹẹta, ati pe iwadii ti n lọ lọwọ lati tuṣu desalẹ ikoko iṣalẹ naa.