Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ Majisreeti agba ilu Ado-Ekiti ti paṣẹ pe kawọn afurasi mẹrin kan lọọ mu obi wọn wa gẹgẹ bii oniduuro lẹyin tawọn ọlọpaa fẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun kan wọn.
Oni Ọlamide, ẹni ọdun mẹtalelogun, lawọn ọlọpaa fẹsun kan pẹlu Samson Shodipẹ, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Ajayi Ajibade toun jẹ ẹni ogun ọdun, ati Akinọla Tolulọpẹ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.
Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale ṣalaye pe ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, lawọn olujẹjọ naa huwa ọhun niluu Iworoko-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, bẹẹ niwadii ọlọpaa fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni wọn.
Nitori bi ẹsun naa ṣe ta ko ofin to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun, eyi tijọba ṣe lọdun 2017, Akinwale ni ki kootu naa fi wọn pamọ sọgba ẹwọn digba ti ẹka to n gba adájọ́ nimọran (DPP), yoo sọ igbesẹ to kan.
Ṣugbọn Amofin Timi Ọmọtọshọ ati Amofin Chris Omokhafe rọ kootu lati faaye beeli silẹ fawọn olujẹjọ ki wọn le maa wa lati ile waa jẹjọ, pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ.
Majisreeti-agba Lanre Owolẹṣọ gba beeli Oni atawọn mẹta to ku pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) ati oniduuro meji niye kan naa, ninu eyi ti ọkan gbọdọ jẹ obi wọn, nigba ti ekeji gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa nipele kẹwaa.
Igbẹjọ yoo tẹsiwaju lọjọ kejila, oṣu to n bọ.