Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n di ẹbi ru ọlọkada kan to fẹẹ ya tirela silẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lagbegbe Ọlọrunṣogo, l’Abẹokuta, to si ṣe bẹẹ ko sabẹ tirela ọhun pẹlu ero meji to gbe, to fi di pe awọn mẹtẹẹta jẹ Ọlọrun nipe lẹsẹkẹsẹ.
Ohun ti awọn tiṣẹlẹ ti ko jinna s’Iyana Mortuary yii toju wọn ṣẹlẹ, sọ ni pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ naa lo waye.
Wọn ni niṣe ni ọlọkada naa n sare, to fẹẹ ya tirela silẹ, nibi to ti n ṣe bẹẹ ni kinni ọhun ti bu u lọwọ, niṣe ni tirela tẹ oun atawọn ero meji to gbe sẹyin ọkọ naa pa.
Alukoro TRACE nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi, fidi iṣẹlẹ yii mule. O ṣalaye pe ọlọkada naa padanu ijanu ẹ nibi to ti n gbiyanju lati ya tirela silẹ ni. O fi kun alaye ẹ pe ẹni to wa tirela ọhun ko duro wo wọn, o ba tiẹ lọ ni.
Ile igbokuu-si to wa ninu ọsibitu Ijaye, l’Abẹokuta, ni wọn gbe awọn oku mẹta naa pamọ si.