Wahala niluu Aye, ọmọ kabiesi ku sinu igbo, lawọn araalu ba ni ọlọpaa lo yinbọn pa a

Florence Babaṣọla

Ara o rọ okun, bẹẹ ni ko rọ adiyẹ bayii niluu Aye, nijọba ibilẹ Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, pẹlu bi awọn araalu ṣe fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn yinbọn pa ọkan lara awọn ọmọ kabiesi ilu naa.

Ọkunrin kan, Jacob Ayọọla, la gbọ pe o kọ iwe ẹsun sawọn ọlọpaa nipa ọba ilu naa, Ọba Mathew Ajala, ati gbogbo ilu lapapọ lori ilẹ kan nibẹ.

A gbọ pe awọn ọlọpaa lati ẹkun kọkanla, iyẹn Zone XI, si lọ siluu naa lati ba wọn yanju ẹ. Ori ilẹ yẹn ni wọn duro si lọjọ yii, aburo kabiesi, Gbenga Ajala, si ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ lorukọ awọn araalu, bo ṣe rojọ tan la gbọ pe o ṣubu lulẹ, ki wọn si to gbe e de ọsibitu, o ti jade laye.

Ọrọ yii bi awọn ọdọ ilu ninu pupọ, bi wọn si ṣe sin oku Gbenga tan lọjọ keji ni wọn ya lọ sile Ayọọla pe afi ko fi ilu silẹ fun awọn. Nigba ti ọrọ naa le ju ni baba yii ko awọn ọmọ pẹlu awọn ọmọ-ọmọ rẹ, ti wọn si sa lọ.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ diẹ, gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Ejigbo tẹlẹ, Ẹnjinnia Yinka Adigun, ṣe wi, ṣe ni Ayọọla lọ sileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, o si ko awọn ọlọpaa wọlu Aye ni nnkan bii aago kan oru.

Lakọlakọ lawọn ọlọpaa naa n yinbọn, ti wọn si fi pampẹ gbe ọpọlọpọ awọn araalu lọjọ yii, laaarọ ọjọ keji ni wọn ba ọkan lara awọn ọmọ kabiesi, Isaiah Ajala, to ti ku sinu igbo.

Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ọlọpaa ti wọn lọ sibẹ ko pa ẹnikankan. O ni ẹsun igbiyanju lati paayan ati idunkooko mọ ẹmi ẹni ni Ayọọla fi kan awọn kan ninu ilu naa, idi si niyi tawọn ọlọpaa fi lọ sibẹ.

Nipa idi ti wọn fi lọ laarin oru, Ọpalọla ṣalaye pe asiko yẹn lawọn ọlọpaa le ri awọn ti Ayọọla fẹsun kan mu, wọn si ti ri mọkanla mu ninu awọn mejila torukọ wọn wa niwaju awọn ọlọpaa bayii.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe ọmọkunrin to n jẹ Isaiah yii gan-an lo ṣa ọkan lara awọn ọlọpaa ti wọn lọ sibẹ ladaa, to si sa lọ lọjọ naa.

O ṣeleri pe iwadii yoo bẹrẹ kiakia lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.

Leave a Reply