Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣe lọọ jalẹkun awọn ṣọọbu kan ninu ọja Bodija loru mọju Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, Alukoro fun ileeṣẹ aṣọbode ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, Ọgbẹni Kayọde Wey, ti sọ pe awọn aṣọbode lo ṣiṣẹ naa loootọ, ṣugbọn awọn eeyan awọn lati ilu Abuja ti i ṣe olu ilu ilẹ yii ni wọn ṣiṣẹ naa, ki i ṣe awọn aṣọbode n’Ibadan.
Ṣugbọn Iyalọja ọja Bodija, Oloye Victoria Onipẹde, ti ṣapejuwe igbesẹ ti awọn agbofinro gbe ọhun gẹgẹ bii ọna lati fara ni araalu.
Yatọ si ọkẹ aimọye apo irẹsi ati ogunlọgọ kẹẹgi ororo ti wọn ko ninu awọn ṣọọbu naa lẹyin ti wọn fipa ja awọn ilẹkun ṣọọbu wọnyi wọle, nnkan bii miliọnu mẹẹẹdogun Naira (#15000) lapapọ owo ta a gbọ pe wọn tun ji ko ninu awọn sọọbu naa.
Ẹkun asun-kawọleri lọpọ ninu awọn to n ṣowo irẹsi tabi ororo ninu ọja Bodija, n’Ibadan, fi aarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, sun, awọn ti iba si rẹ wọn lẹkun ko mọ iru arọwa ti wọn iba pa fun wọn, wọn mọ pe ijọba lo fa sababi ohun to pa wọn lẹkun.
Lọsan-an ọjọ naa lawọn ti ọrọ yii kan pẹlu awọn ara ọja ọhun mi-in lọ si Sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ lati fẹhonu wọn han sijọba ipinlẹ yii.
Ẹnikẹni iba ti mọ pe awọn aṣọbode lo jalẹkun ṣọọbu awọn oniṣowo ni Bodija ti wọn si ko wọn lẹru ọja atowo nla lọ, awọn kọsitọọmu funra wọn ni wọn fi awọn agadagodo mi-in to jẹ tiwọn tun awọn ilẹkun naa ti, ti wọn si tun lẹ iwe mọ ara ilẹkun lati jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn lawọn ṣiṣẹ naa.
Ninu iwe ti wọn lẹ mọ ara awọn ṣọọbu ti wọn ja wọnyi ni wọn ti ṣekilọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ jalẹkun tabi wọ inu awọn ṣọọbu wọnyi lai gba aṣẹ lọwọ awọn, bi eeyan ba dan iru ẹ wo, oluwa ẹ yoo ṣẹwọn ọdun mẹwaa tabi ko fi miliọnu lọna ọgọrun-un naira (N100 m) gbara.
Nigba to n b’ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ aṣọbode ẹkun ipinlẹ Ọyọ ati Ọyọ, Ọgbẹni Kayọde Wey, sọ pe “Awọn eeyan ti pe mi lori ọrọ yẹn lataarọ, ṣugbọn a ko mọ nnkan kan nipa ẹ rara.
“Ki i ṣe awa la ṣiṣẹ yẹn, a ko tiẹ mọ nipa ẹ rara. Awọn ara Abuja lo ṣe e, mi o si mọ iru iroyin ti wọn gbọ ti wọn fi gbe igbesẹ yẹn.”
Ṣugbọn gẹgẹ bii olori ọja, iṣẹlẹ yii ko dun mọ Oloye Victoria ti i ṣe Iyalọja ọja Bodija ninu, o ni ọna lati ni araalu lara nigbesẹ ti awọn aṣoju ijọba apapọ ilẹ yii gbe ọhun.
O ni “Awọn kọsitọọmu lẹ iwe mọ awọn ṣọọbu ti wọn ja lati fi han pe awọn lawọn ko ọja inu awọn ṣọọbu wọnyẹn. Nitori naa, iṣẹlẹ yẹn ti kuro ni pe wọn jale.
“Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ fun mi, ni nnkan bii aago mẹta oru lawọn kọsitọọmu waa jalẹkun ṣọọbu awọn onirẹsi kan ti wọn si ko awọn irẹsi wọn lọ.
“Ki i ṣe gbogbo ṣọọbu ni wọn ja, awọn ṣọọbu ti wọn ko irẹsi ti wọn ko wa lati ilẹ okeere si nikan ni. Ṣugbọn apo irẹsi ti wọn ko lọ ko to tirela mẹẹẹdogun (15) ti awọn oniroyin n pariwo nitori aago mẹta oru ni wọn wa, ko si ṣee ṣe ki wọn ti sare ko aduru nnkan bẹẹ yẹn laarin asiko yẹn si aarọ yẹn nitori bii wakati meji lawọn alabaaru maa n lo lati ko tirela apo irẹsi kan tan.
“Loootọ, a mọ pe ọja to ta ko ofin ni irẹsi ti wọn ba ko wa lati ilẹ okeere nitori ijọba ti ṣe irẹsi kiko wọ ilẹ yii lati orileede mi-in leewọ, ṣugbọn ta a ba maa sọ eyi to jẹ ootọ ọrọ, inira ti ofin yii n mu ba araalu pọ ju anfaani ibẹ lọ.
“Erongba ijọba pẹlu ofin yẹn ni lati jẹ ki awọn eeyan maa ra nnkan ti awọn awa funra wa ba n pese lorileede yii. Ṣugbọn irẹsi ti a n gbin lorileede yii ko ti i to wa a jẹ debi ti ijọba maa fofin de ti ilẹ okeere.
“Ọpọ eeyan ni ko mọ pe ki i ṣe anfaani kekere ni irẹsi ilẹ okeere n ṣe fun wa. Idi ni pe, ni gbogbo igba ti ijọba ba ti ti ẹnu ibode pa, ti awọn eeyan ko raaye ko irẹsi wọle mọ, niṣe nirẹsi wa nilẹ yii maa n gbowo lori, nigba to jẹ pe irẹsi ti a n gbin nilẹ yii ko ti to waa jẹ.
“Irẹsi tiwa-n-tiwa wọn ju tilẹ okeere lọ. Nigba ti ijọba ti bode pa, a n ra kongo kan irẹsi ilẹ yii ni ẹgbẹrin naira (N800). Ṣugbọn nigba ti wọn ṣi bode, ti irẹsi ilẹ okeere de, ẹgbẹrin naira ni kongo kan oun naa, iyẹn lo mu ki owo irẹsi tiwa-n-tiwa ja wa silẹ pẹlu aadọta naira (N50). Awọn to n tiraka lati ko awọn ọja wa lati ilẹ okeere ni wọn n jẹ ki adinku ba owo ọja bayii
“Iranlọwọ ijọba apapọ lawa oniṣowo nilo, lati jẹ ko rọrun fun wa lati maa ri ọja ra nirọrun, ki gbogbo araalu to taja naa ma baa maa ra a pẹlu owo gọbọi nitori owo ọhun naa ko si nibikankan.”