Faith Adebọla, Eko
Ara ni wọn lo ta baale ile ẹni ọdun mẹrinlelọgọta kan, Osita Anwuanwu, nigba to gbọ pe ale oun, Juliet Emezue, ti wa nile ọti ọrẹ rẹ kan n’Ikọtun, lọkunrin naa fi sare de’bẹ, ṣugbọn ohun to ro kọ lo ba, tori ibi to ti n ja sobinrin lọwọ lo ti fidi janlẹ, lo ba dagbere faye.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọmọ oloogbe naa, Linda Anwuanwu, toun ati baba ẹ jọ n gbe ile kan ti wọn haaya ni Opopona Temitọpẹ, nitosi Governor’s Road, n’Ikọtun, lo sare jannajanna de teṣan ọlọpaa Ikọtun ni nnkan bii aago meje alẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, pe awọn obinrin meji kan ti pa baba oun sile ọti, o ni wọn lu baba oun pa nibi ti wọn ti n ja.
Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa tẹle ọmọbinrin naa lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn si ba baba naa, Osita, to na gbalaja silẹ, pẹlu awọn ero to pe le wọn lori.
Wọn lawọn ọlọpaa sare fi mọto wọn gbe ọkunrin naa lọ si Ọsibitu Jẹnẹra Igando, ibẹ ni wọn ti sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa naa ti ku. Eyi lo mu ki wọn fi pampẹ ofin gbe awọn obinrin mejeeji ti wọn fẹsun kan pe wọn ba oloogbe naa ja.
Ninu iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, wọn ni ọrẹ ni Ngozi Emezue, ẹni ọdun mejidinlogoji to ni ile ọti tiṣẹlẹ ọhun ti waye ati Juliet Eguebor, ẹni ọdun marundinlogoji toun ati oloogbe naa jọ n yan ara wọn lale.
Wọn ni Ngozi ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ko pẹ ti ọrẹ oun de lati waa ba oun ṣere, ṣadeede lawọn ri oloogbe naa to sare de, to si fija pẹẹta pẹlu ale rẹ atoun, wọn lo fẹsun kan wọn pe o ni lati jẹ pe ọkunrin mi-in ni Juliet waa pade nile ọti oun ni. Ọrọ yii ni wọn fa titi, lọrọ ba dija, ibi ti wọn si ti n ba ara wọn ja ni wọn lọkunrin naa ti fidi janlẹ, lo ba ṣubu gbalaja sibẹ. O ni ko si ẹjẹ tabi apa ọgbẹ kan lara ọkunrin naa, awọn si kọ lawọn pa a, o ku funra ẹ ni.
Amọ ṣa, boya o ku funra ẹ ni o tabi wọn ṣe e leṣe ni, kọmiṣanna ọlọpaa ti ni ki wọn taari awọn afurasi ọdaran mejeeji, Ngozi ati Juliet, sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ibẹ si ni wọn aa ti tubọ raaye ṣalaye daadaa fawọn oluṣewadii, ki wọn too lọọ tun alaye naa ṣe niwaju adajọ laipẹ.