Nitori ṣọja atawọn mi-in ti wọn ji gbe, awọn agbofinro ya lu igbo ọna Ibadan s’Ijẹbu-Ode 

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ba a ṣe n wi yii, inu igbo ni ikọ oluwadii laarin awọn agbofinro ipinlẹ Ọyọ wa, lati tu ṣọja atawọn obinrin meji ti awọn ajinigbe ji gbe silẹ ninu igbekun.

Ikọ awọn agbofinro ọhun, eyi ti awọn ọlọpaa lewaju ẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ Ọjọruu, Wẹsidee yii, lo ko ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Amọtẹkun atawọn fijilante pẹlu awọn agbaagba ọdẹ ibilẹ to wa nijọba ibilẹ Oluyọle, ni Idi-Ayunrẹ, n’Ibadan, sinu.

Akọroyin ALAROYE atawọn oniroyin mi-in pẹlu awọn agbofinro ninu irinajo ọhun. O kere tan, afurasi ọdaran mẹta lo fẹsẹ fẹ ẹ nigba ti wọn gburoo awọn ọlọpaa to n bọ lọọọkan.

Meji ninu wọn lo n da maaluu kiri ninu igbo nla naa, bi wọn ṣe ri awọn agbofinro lọọọkan ni wọn sọ ede ajejeji kan si awọn maaluu ọhun, ti awọn nnkan ọsin naa si ki ere buruku mọlẹ lojiji, ti wọn bẹrẹ si i sare tagbara tagbara.

 

“Lẹẹkan naa lawọn darandaran wọnyi poora mọ aarin wọn, ti wọn si ṣe bẹẹ ra sinu aginju igbo naa pẹlu bi akitiyan awọn agbofinro lati ba awọn olowo wọn sọrọ ko ṣe seso rere debi ti wọn yoo ri wọn mu.

Lẹyin wakati meji sigba naa la ri ọkunrin kan naa lọọọkan to bẹrẹ mọlẹ to n sare lọ. Lojiji lawọn ọlọpaa to gba ya a ko deede ri i mọ, ti wọn ko si tun gburoo ẹsẹ rẹ mọ titi ti irinajo ọhun fi pari.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ kejila, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, lawọn ọbayejẹ kan ji obinrin ṣọja kan, Bọlanle Ogunrinde, atawọn meji mi-in ti wọn n jẹ Abọsẹde Adebayọ ati Abilekọ Ọkẹowo gbe labule ti wọn n pe ni Onipẹẹ, lọna to ti Ibadan lọ s’Ijẹbu-Ode nigba tawọn eeyan naa n ti Ibadan lọ sọna Ijẹbu-Ode pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota wọn ti nọmba rẹ jẹ AGL 66 FY.

Iwadii akọroyin wa fidi ẹ mulẹ pe lati ọjọ Aje, Mọnde, ọhun lawọn agbofinro ko ti sun, ti wọn ko wo lori itọpinpin awọn olubi ẹda naa.

Laarin gbugbun aginju naa lapata nla kan wa, ninu eyi ti awọn agbofinro to wọ inu ẹ lọ ti ri oogun ara riro ati beba ti awọn eeyan kan tẹ silẹ lati fi ṣe ibusun, eyi to fi han pe awọn afurasi ọdaran kan n fara pamọ si aaye naa. O si ṣee ṣe ko jẹ pe ibẹ lawọn ọbayejẹ naa kọkọ gbe awọn ẹni ẹlẹni pamọ si ki wọn too gbe wọn lọ sibomi-in gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn ajinigbe ki i gbe awọn eeyan ti wọn ba ji gbe duro soju kan.

Lara awọn ikọ ọlọpaa to n fi tọsan toru wa awọn ọdaran naa ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe, iyẹn Anti Kidnapping Squard, atawọn ikọ to n gbogun ti iwa ọdaran bii Puff Arder, Skynet, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lati ọjọ Aje, Mọnde yii, lawọn kan ninu ikọ AKS, iyẹn ẹka ọlọpaa to n gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe ti fi inu igbo nla to so Ibadan pọ mọ Ijẹbu-Ode ṣebugbe, to jẹ pe ibẹ ni wọn n sun, ti wọn si n tẹsiwaju ninu iṣẹ iwadii wọn ninu igbo naa bi wọn ba ti ji.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin irinajo naa ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ yii, AC Ops, iyẹn igbakeji ọga agba ọlọpaa to n mojuto iṣọwọ-ṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Ọyọ, ACP Gbenga Ojo, sọ pe “gẹgẹ ba a ṣe mọ, awọn iṣẹlẹ ijinigbe waye lẹnu ọjọ mẹta yii lọna Ibadan si Ijẹbu-Ode, eyi lo jẹ ka fọn awọn ọlọpaa sita pẹlu iranlọwọ awọn fijilante atawọn ọdẹ ibilẹ.

“Bo tilẹ jẹ pe a ko ri ẹnikan kan mu, a ko ni i kaaarẹ lori akitiyan wa lati gba awọn eeyan ti wọn ji gbe silẹ laaye. Loorekoore la oo maa fọ gbogbo inu igbo ti awọn oniṣẹ ibi n fara pamọ si bayii nitori a ko fẹẹ maa duro de awọn ọdaran wọnyi loju titi mọ bayii, a fẹẹ lọọ maa ka wọn mọnu igbo ni.”

Leave a Reply