Ọọni yan Toyin Kọlade ni Iyalaje Oodua

Florence Babaṣọla

 

Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti kede oludari apapọ ọdun Aje, Ọmọọbabinrin (Dokita) Oluwatoyin Kọlade, gẹgẹ bii Iyalaje Oodua.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe Ọọni, Moses Ọlafare, fi sita lo ti ṣapejuwe obinrin naa gẹgẹ bii oniṣowo pataki to bẹrẹ latibi kekere lọdun marundinlogoji sẹyin niluu abinibi rẹ, Ileṣa.

Ọọni ṣalaye pe lati ọdun 2017 ti Dokita Kọlade ti di aṣoju Ọdun Aje lo ti n ṣe takuntakun lori idagbasoke iran Yoruba, to si jẹ pe igba marun-un ti wọn ti ṣe e jẹ eyi to wu ni lori pupọ.

Kabiesi ni aṣoju rere to ni ọwọ pupọ fun awọn ori-ade ni Dokita Kọlade, to si jẹ obinrin to nikora-ẹni-nijaanu, bẹẹ lo si mu ọrọ mọlẹbi rẹ lọkun-unkundun.

Atẹjade naa fi kun un pe ninu oṣu keje, ọdun yii, ni ayẹyẹ iwuye yoo waye fun Dokita Kọlade gẹgẹ bii Iyalaje Oodua.

Leave a Reply