Faith Adebọla, Eko
Fatai Kalejaiye, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ti wọn lo n gbe Ojule kọkandinlogun, adugbo Igbẹlara, n’Ikorodu, ti ko sakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko. Wọn ni ibi to ti n ṣe oro iwẹgbẹ ti wọn maa n ṣe fọmọ ẹgbẹ tuntun lọwọ ni wọn ka oun ati Kọlapọ Ayeobasan mọ, Kọlapọ ni wọn ṣẹṣẹ fẹẹ mu wẹgbẹ okunkun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, sọ ninu atẹjade kan pe lẹhinkule ile ti Kọlapọ n gbe l’Ojule Kẹrin, Opopona Anifowoṣe, Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni wọn ti n ṣeto imu-ni-wẹgbẹ naa loru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ ni wọn fẹẹ mu un wọ.
O lawọn alaamulegbe laduugbo tiṣẹlẹ naa ti n waye ni wọn dọgbọn tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago loru ọhun, lawọn ọlọpaa lati teṣan Ikorodu ba gbera lọ sibẹ, kongẹ wọn ni wọn ṣe, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.
O lawọn agbofinro ba fila, ẹwu dudu ti wọn ya ami ẹgbẹ okunkun ẹyẹ si, bileedi ti wọn fi n ṣa ara wọn ni gbẹnrẹ, oogun abẹnu gọngọ atawọn nnkan mimu ti wọn fura pe egboogi oloro ni wọn po pọ sinu wọn lọwọ wọn.
Wọn tun ni Fatai ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ loun, oun si joye ninu ẹgbẹ naa.
Ṣa, ati Fatai to fẹẹ mu Kọlapọ wẹgbẹ, ati Kọlapọ to fẹẹ dọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’, atawọn ẹsibiiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ ti wọn fi n ṣeto iwẹgbẹ, gbogbo wọn ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba bayii, ibẹ ni kaluku yoo ti kọkọ ṣalaye ara ẹ fawọn to n ṣewadii, ki ọrọ wọn too dewaju adajọ laipẹ, bii Alukoro Adejọbi ṣe wi.