Awọn ajinigbe ji Alaga gbe lọna oko rẹ l’Oke-Onigbin, ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Oniṣowo pataki kan, Alhaji Alaga Ọlayẹmi, lawọn ajinigbe bii meje ji gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lọna oko rẹ niluu Oke-Onigbin, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara.

Alaga atawọn ọmọọṣẹ rẹ to tẹle e lawọn ajinigbe naa fibọn da lọna ni nnkan bii aago meje irọlẹ. Gbogbo akitiyan awọn to kọwọọrin pẹlu ọkunrin naa lati doola ẹmi rẹ lo ja si pabo, ṣe lawọn ajinigbe naa gbe e lọ raurau.

Titi di asiko yii, ko ti i sẹni to mọ pato ibi to wa.

Awọn oṣiṣẹ rẹ mejeeji to wa pẹlu rẹ lọjọ naa paapaa ko fara ire lọ, ṣe lawọn ajinigbe naa ṣa wọn lada yannayanna lasiko ti wọn n gbiyanju lati wọya ija pẹlu wọn lọna ati gba ọga wọn silẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn ọdẹ ilu pẹlu awọn agbofinro kan ti ya wọ inu igbo to wa lagbegbe tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lati gba ọkunrin ti wọn ji gbe naa pada.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni Ọga ọlọpaa, CP Mohammed Lawal Bagega, ti gbe ikọ kan dide lati doola Alaga, ati lati mu awọn ọdaran naa.

Leave a Reply