Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn agbebọn ti ji alakooso fun eto ọgbin nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, Ebenezer Busuyi, lẹyin ọsẹ kan ti wọn ji Ọbadu tilu Ilẹmẹṣọ, Ọba David Oyewumi.
Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ naa waye loju ọna Ilawẹ-Ekiti si Ẹrijiyan-Ekiti, lasiko ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC) naa n lọ pẹlu mọto ẹ.
A gbọ pe lẹyin ti wọn ji i gbe tan lawọn eeyan too mọ nigba ti wọn deede ri mọto ẹ lẹgbẹẹ titi, to si han gbangba pe wọn ti wọ ọ wọ inu igbo.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa Rapid Response Squad, ikọ Amọtẹkun, atawọn ọdẹ ti n ṣiṣẹ takuntakun ninu gbogbo igbo to wa lagbegbe naa.
O ni aago mẹfa irọle niṣẹlẹ naa waye, ko si sẹni to mọ ibi ti wọn gbe oloṣelu naa lọ.
O waa ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i gba kawọn ajinigbe sọ Ekiti di ibugbe wọn, bẹẹ lo gba awọn eeyan niyanju lati maa ṣọra ni gbogbo igba.