Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Yatọ si iroyin ofege to gbode tẹlẹ nipa akoko idibo sipo alaga ati kansilọ nipinlẹ Ogun, ajọ eleto idibo nipinlẹ naa, ‘Ogun State Independent Electoral Commission’ (OGSIEC), ti kede pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ni idibo si ipo alaga ati kansilọ yoo waye kaakiri ipinlẹ Ogun.
Ninu atẹjade ti Alaga OGSIEC, Ọgbẹni Babatunde Osibodu, fi ọwọ si, to si fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu kẹrin, lo ti ṣalaye pe ki nnkan le lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ajọ eleto yii ti ṣeto ipade awọn oniroyin ti yoo waye lọjọ kẹrin, oṣu karun-un, ọdun 2021.
Osibodu sọ pe nibi ipade naa ti yoo waye ni gbọngban sinima, June 12 Cultural Centre, Kutọ, l’Abẹokuta, laaago mẹwaa aarọ lawọn yoo ti ṣalaye awọn ọna ti ibo naa yoo gba waye fawọn to fẹẹ kopa atawọn araalu lapapọ.
Alaga ajọ yii waa rọ awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ kopa ninu ibo naa pe ki wọn ri i daju pe wọn ran aṣoju wa sibi ipade oniroyin yii, o kere tan, aṣoju meji, ki wọn le mọ bi ohun gbogbo yoo ṣe lọ.
O ni kawọn to n bọ ma gbagbe lati tẹle ofin Korona, ki wọn mura nilana to ba ofin Koro lọ.