Wọn dana sun afurasi adigunjale pẹlu ọkada rẹ n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi adigunjale jale kan pade iku airotẹlẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, lagbegbe Maraba, niluu Ilọrin.

Ọkunrin ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ, lawọn ọdọ kan ya bo, Wọn kọkọ dana sun ọkada rẹ, lẹyin naa ni wọn gba ti i. Bi wọn ṣe da igi bo o ni wọn n ju nnkan mọ ọn titi ti ko fi le dide.

Kawọn eeyan too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti gbe taya ati epo bẹntiroolu de, loju-ẹsẹ ni wọn ju u si i lọrun, ti wọn si kana lu u.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣewadii iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply