Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Rasheed Ayinde; ẹni ogun ọdun, ati Matthew Ọladipupọ, ẹni ọdun mẹtalelogun, lẹ n wo yii, awọn ọlọpaa lo mu wọn lagbegbe Onipaanu, l’Ọta, ipinlẹ Ogun, nigba ti wọn fẹẹ lọọ jale laduugbo naa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii.
DPO teṣan ọlọpaa Onipaanu, CSP Bamidele Job atawọn ikọ ẹ ni wọn n paara adugbo wọn lati da aabo bo ibẹ, nigba naa ni wọn ri awọn meji yii lọri ọkada, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ naa.
Bawọn gende meji yii ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn gbiyanju lati yipada, wọn fẹẹ gba ọna mi-in ki wọn ma baa pade awọn agbofinro yii.
Eyi lawọn ọlọpaa ṣe fura si wọn, ti wọn si da wọn duro, ni wọn ba bẹrẹ si i fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Rasheed ati Matthew jẹwọ fawọn ọlọpaa pe adigunjale lawọn, wọn ni Abẹokuta lawọn n gbe, ibẹ lawọn ti maa n waa jale l’Atan Ọta, Onipaanu ati agbegbe rẹ. Wọn fi kun un pe oko ole kan lawọn n lọ tawọn fi bọ sọwọ ọlọpaa yii.
Nigba ti wọn yẹ ara wọn wo, ibọn ilewọ ibilẹ kan pẹlu ọta ibọn ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn, wọn tun ba awọn oogun oriṣiiriṣii ninu apo ti wọn gbe lọwọ pẹlu.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi sọ pe ọga awọn, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe kawọn ko awọn meji yii lọ sẹka iwadii to lọọrin fun itẹsiwaju itọpinpin nipa wọn.