Faith Adebọla
Awọn ọdọ kan, awọn ọlọkada ati ẹgbẹ awọn onimọto nipinlẹ Ekiti pe jọ si gbagede Fajuyi Park, Ado-Ekiti, lowurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, wọn ṣe iwọde ta ko idasilẹ ‘Orilẹ-ede Oodua’, ati bi ẹya Yoruba ṣe fẹẹ ya kuro lara Naijiria.
Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Yoruba Appraisa Forum (YAF) lo ṣagbatẹru iwọde ọhun.
Lati Fajuyi Park lawọn ero naa ti fẹsẹ rin biriiji Okesa kọja sigboro ilu Ado-Ekiti, wọn si di ẹgbẹ kan ọna marosẹ to gba ilu naa kọja.
Bi wọn ṣe n kọrin lati fi erongba wọn han, bẹẹ ni wọn gbe oriṣiiriṣii akọle dani, lara akọle naa ka pe: “Naijiria lawa gbagbọ, oun la duro fun,” “Ẹ jẹ ka wa papọ, ka nifẹẹ ara wa. Ko si ba a ṣe le ṣaṣeyọri bii orileede kan lai si ifẹ.” Akọle mi-in ka pe: “Ẹkan omi la maa jẹ ta a ba da duro, ta a ba wa papọ la maa di odo nla.”
Aṣaaju ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Adeṣina Animaṣahun, ninu ọrọ rẹ ni Fajuyi Park lori igbesẹ ti wọn gbe yii sọ pe o pọn dandan kawọn jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn o fara mọ iyapa, awọn o si nifẹẹ si bi Sunday Igboho (Sunday Adeyẹmọ) ṣe n polongo pe ki Yoruba da duro lati da orileede Oodua silẹ.
O lawọn tun kọminu si awọn ẹgbẹ IPOB ti Nnamdi Kanu ṣolori rẹ nilẹ Ibo, o ni ẹgbẹ naa lo wa lẹyin didana sun dukia ati ifẹmiṣofo to n waye leralera lagbegbe wọn lọhun-un, ati pe orin ti Nnambi Kanu n kọ ni Sunday Igboho n gbe, awọn o si fara mọ ọn.
“Naijiria ko gbọdọ di Somalia, ko siṣọkan ni Somalia lonii latari ogun, niṣe lawọn ti wọn fẹẹ ka ya kuro lara Naijiria yii fẹẹ da yanpọnyanrin silẹ o.
“A fẹ kawọn ọmọọya wa nilẹ Yoruba ti wọn n gbero kinni yii tun ero wọn pa o. Ohun toju wa ri, ohun ta a padanu, lasiko iwọde EndSARS to kọja ki i ṣe kekere, ọpọ tiriliọnu naira ni, yatọ si ẹmi eeyan to ṣofo.