Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Rivers, Amofin Nyesom Wike, ti sokọ ọrọ si ijọba apapọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari n dari, o ni alaibikita ni wọn, iṣe wọn fihan pe oku eeyan ibaa kun gbogbo opopona ni Naijiria, ko ṣe wọn ni nnkan kan.
Bakan naa ni gomina ọhun ke si gbogbo awọn agbaagba atawọn ọtọkulu to ba nifẹẹ Naijiria dọkan lati dide si iṣoro ọrọ aabo to fẹju kẹkẹ yii, ki wọn si ma jẹ ki orileede yii pin si wẹwẹ, tori ti wọn o ba ṣe bẹẹ, ijọba to n ṣakoso lọwọ yii ko kọ ki ẹjẹ ṣan bii omi.
Nile ijọba ipinlẹ Rivers ni Wike ti sọrọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, nigba to n gba igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ PDP, ẹkun ti Guusu, lalejo lọfiisi rẹ.
Wike ni arun oju ni, ko si lọrọ iyan jija ninu rara, pe ijọba apapọ ko lẹmii ifọrọ-rora-ẹni, wọn o nimọlara bi awọn nnkan to n ṣẹlẹ yii ṣe n ri lara awọn araalu.
“Awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe ijọba apapọ tẹgbẹ wọn n dari yii maa yanju iṣoro aabo to mẹhẹ. Ṣugbọn ojoojumọ lawọn eeyan n ku, ojumọ kan o mọ ki ifẹmiṣofo ma ṣẹlẹ. Igba wo gan-an ni wọn waa fẹẹ yanju ẹ?
“Dipo ki wọn tuuba fawọn ọmọ Naijiria, ki wọn jẹwọ pe awọn ti ja wọn kulẹ ninu gbogbo ileri ti wọn ṣe fun wọn, ki wọn si yẹba kuro nipo agbara na, wọn ko ṣe bẹẹ.
Gbogbo ẹni ti ọrọ orileede yii ba n jẹ lọkan, gbogbo ẹni to ba ṣi nigbagbọ ninu orileede yii gbọdọ dide wuya, ki wọn jẹ ka ṣe nnkan kan nipa ọrọ yii, aijẹ bẹẹ, gbogbo wa lọrọ naa maa kan o.”
Gomina naa tun sọ pe ailoootọ ati abosi lo n yọ awọn onṣejọba lẹnu, eyi lo fa a tijọba apapọ naa ko fi le soootọ faraye pe omi ti pọ ju ọka lọ fawọn. O ni kawọn eeyan yaa tọju kaadi idibo wọn daadaa, ki wọn le lo o lati le ijọba ti o ṣe wọn loore yii danu.
“To ba jẹ orileede ti wọn ti mọyi ọwọ ati ododo ni Naijiria ni, ijọba apapọ tẹgbẹ APC n dari yii, ti wọn o tiẹ bikita bi oku eeyan kun gbogbo ọna ati opopona orileede yii, yẹ ki wọn kuro nipo jẹẹjẹ ni. Ohun to daa ju lọ fun wọn niyẹn.”