Faith Adebọla, Eko
Yatọ si bawọn kan ṣe ro, wọn ti fidi ẹ mulẹ pe iku to mu Pasitọ Dare Adeboye, ọmọ gbajugbaju ojiṣẹ Oluwa ati Oludari agba ijọ Ridiimu kari aye nni, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, lọ ki i ṣe arun Koronafairọọsi rara.
Ọwurọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni iroyin iku ọmọ kẹta, ọkunrin keji fun Baba Adeboye yii gba igboro kan, lẹni ọdun kejilelogun.
Bi iku naa ṣe ṣadeede waye lojiji, ti oloogbe naa ko sọ pe aarẹ kan n ṣe oun tẹlẹ, to si waasu fawọn ọdọ ni ọjọ to ṣaaju iku rẹ yii, lo mu kawọn eeyan maa fura pe boya arun Korona lo kọ lu u to si mu ẹmi rẹ lọ.
Ṣugbọn ẹgbẹ awọn pasitọ ijọ Ridiimu, Pastors’ Seed Family ti sọ pe rumọọsi lọrọ naa, ki i ṣe ootọ rara.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, wọn ni ko sohun to jọ ọrọ Korona ninu iku to mu ọkan lara awọn lọ ọhun, wọn ni oju oorun ni Dare Adeboye wa ti iku fi mu un lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni ile rẹ to wa ni ilu Eket, nipinlẹ Akwa Ibom.
Atẹjade naa ka pe: “Pẹlu ẹdun ọkan gidi la fi kede ipapoda ọmọ wa olufẹ, arakunrin wa, ọkọ ati baba, Oluwadamilare Temitayọ Adeboye, to re kọja lọọ sọdọ Oluwa ni ọjọ kẹrin, oṣu karun-un, ọdun 2021.
“Oloogbe yii gbe igbe aye rere, o si ṣiṣẹ sin Oluwa tọkan-tara, ọlawọ ni, aṣaaju ti ki i bẹru si ni. Oluwa fi ẹbun ọmọ mẹta ati iyawo kan ta a lọrẹ.
“Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ yii ka wa lara gidi, sibẹ idakọro wa wa ninu Jesu Kristi, a si ni idaniloju pe lọjọ kan a maa pade nibi ti ko ni i si irora kankan mọ.”