Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari bi igbimọ Oloye Kemta(Kemta Council Of Chiefs) nipinlẹ Ogun, ṣe ni awọn ti yọ Ọba Adetokunbọ Tẹjuoṣo nipo baalẹ tawọn fi i jẹ, ti wọn tun ni awọn baalẹ marundinlọgọrin ti Sẹnetọ Ibikunle Amosun sọ di ọba lọdun 2019 ki i ṣe ọba, awọn tọrọ naa kan ti koro oju si bi wọn ṣe pe wọn ni baalẹ, wọn lọba alade lawọn.
Ṣe igbimọ oloye ni Kemta ti fi atẹjade sita lọsẹ to kọja, ninu eyi ti wọn ti ni awọn ti yọ Tẹjuoṣo, baalẹ Adabọnyin, l’Orile-Kemta, nipo baalẹ, bẹẹ ni kẹnikẹni ma ṣe pe e lọba tabi Olu Orile Kemta to n pe ara ẹ, nitori baalẹ lawọn fi i jẹ ki Amosun too sọ oun atawọn yooku rẹ dọba lọdun 2019.
Awọn oloye Kemta fi kun un pe ijọba Gomina Dapọ Abiọdun gbe igbimọ oluwadii iyansipo awọn ọba naa kalẹ, wọn si ri i pe ọna ti wọn gba yan wọn ko tọna, ijọba si paṣẹ pe ki wọn pada sipo baalẹ, ki wọn yee pe ara wọn lọba mọ.
Nigba to n sọrọ lori ohun tawọn Kemta fi sita yii, ọkan ninu awọn ọba ti Amosun yan naa, Ọba Tanimọwo Fọlarin, Olu Ijẹbu Muṣin to tun jẹ akọwe awọn ọba marundinlọgọrin naa, sọ lorukọ awọn ọba yooku pe awọn ko ba ma sọrọ, to ba jẹ ti Adabọnyin tawọn ọlọpaa mu nitori ẹsun jibiti nikan ni. Wọn ni ṣugbọn bawọn oloye Kemta ṣe n pe awọn ni baalẹ lẹyin tawọn ti di ọba ko ṣee dakẹ si, ohun to jẹ kawọn fesi niyẹn.
Ọba Tanimọwo ti sọ pe ọjọ kẹtala, oṣu karun-un, ọdun 2019, ni Amosun ti sọ awọn di ọba, tawọn kuro nipo baalẹ.
Wọn ni ọjọ kẹfa, oṣu keji, ọdun 2020, ni kootu paṣẹ pe ki ọrọ wa bo ṣe wa tẹlẹ (status quo), eyi to tumọ si pe bo ṣe wa latigba tawọn ti jọba, titi digba ti kootu yoo fi gbe idajọ mi-in jade. Wọn ni ko tumọ si pe kawọn pada sipo baalẹ. ALAROYE pe Tẹjuoṣo ti wọn lawọn yọ loye, lori foonu laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ojọ kẹwaa, oṣu karun-un yii, lati gbọ ero rẹ nipa iyọnipo naa, bayii lọkunrin naa wi.
‘’ Aimọkan lo n da wọn laaamu, nibo ni wọn ti lagbara lati yọ mi loye, nigba tijọba ti gbe ote le wọn lati ọdun 2017, pe ki wọn ma da si ọrọ ọba ati yiyan baalẹ mọ nipinlẹ Ogun, emi dẹ jọba ni 2019.
‘’Awọn kọ ni wọn fi mi jọba o, awọn dẹ kọ ni wọn fi mi jẹ baalẹ. Ogboni ni wọn, ile Ogboni la mọ wọn si, ko si nnkan to n jẹ Traditional Council kankan nibi kan.
‘’ Emi ṣi ni Olu Orile Kemta, Adabọnyin, ẹnikan ko yọ mi loye’’
Nipa ibi ti ẹsun jibiti ibasun ti wọn fi kan an de duro, Adetokunbọ ṣalaye pe ko sohun to n jẹ ẹsun jibiti lọrọ oun. O ni awọn kan ni wọn bẹrẹ ọtẹ naa lati tabuku oun lawujọ, ati lati jẹ koun dakẹ lori Ilẹ Olominira Yoruba toun n polongo ẹ kiri.