Awọn gomina ilẹ Yoruba, Ibo ati Naija Delta fofin de dida maaluu kiri lawọn ipinlẹ wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi a ba yọwọ Gomina Adegboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun, ati Gomina Ben Ayade ti ipinlẹ Cross River ti wọn ko si nibi ipade ti awọn gomina lati apa ilẹ Yoruba, ilẹ Ibo ati Naija Delta, ṣe niluu Asaba, ni Delta, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, gomina mẹtadinlogun ni wọn para-pọ, ti wọn lawọn ko fara mọ ai si aabo nilẹ yii mọ, awọn si lodi si fifi ẹran jẹko kiri igboro lawọn ipinlẹ awọn.

Awọn gomina ti wọn kora jọ labẹ orukọ wọn, ‘Southern Nigeria Governors Forum’(SNGF) ninu eyi ta a ti ri Akeredolu lati Ondo ti i ṣe Alaga wọn, Dapọ Abiọdun lati Ogun, Babajide Sanwo-Olu tilu Eko atawọn mi-in, fẹnu ko lori koko ọrọ mejila ninu ohun to n daamu ọrọ aje ati aabo Naijira. Akeredolu lo ka a jade pe,

‘’A ṣakiyesi pe awọn Fulani darandaran atawọn janduku to n wa si ẹkun Guusu ilẹ wa n ṣakoba fun aabo ati ọrọ aje wa, eyi n fa ọwọngogo ounjẹ ati aisi ibale ọkan. Fun idi eyi, a ti fofin de dida maaluu kiri ni gbangba igboro kaakiri apa Guusu Naijiria (Awọn ilẹ Yoruba, Ibo ati Naija Delta)

Wọn tun fẹnuko, pe Buhari ni lati dide bayii, ko ṣe atunto Naijiria nipa awọn ọlọpaa ipinlẹ. Wọn lawọn fẹ ko wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ileeṣẹ kan naa to nilo ki wọn tun nnkan to nibẹ, yatọ si bo ṣe wa lati ọdun gbọọrọ, to jẹ pe awọn kan ni wọn n jere ibẹ.

Ko tan sibẹ, ofin ma jade lawọn asiko kan ti ijọba apapọ tun ṣẹṣẹ bẹrẹ, ti wọn ni nitori Korona ni, awọn gomina yii sọ pe ijọba apapọ yoo ni lati da ọrọ naa ro, nitori awọn akoba ti yoo ṣe fun ọrọ aje. Wọn waa ni ki Aarẹ Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori aabo to dojuru yii, ti ohun gbogbo si ti polukurumuṣu

Aibalẹ ọkan to kari orilẹ-ede yii, nitori ijinigbe ati idojukọ awọn darandaran lawọn gomina yii lawọn ko ṣe fẹẹ dakẹ mọ, ti wọn tori ẹ bẹrẹ Amọtẹkun nilẹ Yoruba, ti Ebubeagu si wa fawọn ẹkun Guusu Ila-Oorun ni tiwọn.

Ṣugbọn bi ipade naa ko ba ṣe da ifọkanbalẹ pada sọkan awọn eeyan to, ti igbagbọ ninu awọn gomina to gbe e kalẹ ko ba si tun kun rẹrẹ to, ẹru to n ba awọn araalu gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ ọ lori ayelujara ni pe bawo lofin tawọn gomina ṣe yii yoo ṣe mulẹ, nigba to jẹ Aarẹ ko kọbi ara si ohun to n ṣẹlẹ gbogbo.

Awọn mi-in sọ pe pipe ipade ko nira, titẹle ohun ti wọn fẹnuko si nibẹ ni pataki. Wọn ni atunto wo lawọn gomina yii n wi, ṣe iru eyi tawọn ọmọ Naijiria n beere fun ni tabi eyi to jẹ ijọba wọn ni yoo jere rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan gboriyin fawọn gomina yii pe wọn tiẹ kora jọ, wọn sọrọ soke, sibẹ, awọn ti wọn sọ pe ipade naa ti pẹ ko too waye lo pọ ju.

Ṣa, ayipada ti ipade yii da le lori lawọn eeyan n reti, paapaa lori ọrọ awọn Fulani atawọn agbebọn to n ji ni gbe kiri.

Leave a Reply