Faith Adebọla
Awọn eeyan binu nitori Uduak Ukpan, ọmọkunrin to pa akẹkọọ yunifasiti, tawọn ọlọpaa n ṣe bii ọba. Wọn ni ọmọkunrin naa ko jọ ẹni to wa latimọle rara, oju rẹ n dan, aṣọ to wọ sọrun tuntun, ko si jọ arufin rara. Wọn ni o da bii pe ọmọkunrin naa ni baba nigbẹẹjọ ni awọn ọlọpaa ko ṣe fọwọ kan an, ti wọn ṣi n ṣe e bii ọba. Wọn ni nigba ti wọn mu Macaroni atawọn ẹgbẹ ẹ ti wọn n ṣewọde lọjọsi, iya nla ni wọn fi jẹ wọn, lai jẹ pe wọn paayan, ṣugbọn ti wọn ko ṣe bẹẹ fun odaran to paayan.
Ọrọ yii waye nigba ti awọn ọlọpaa ṣafihan rẹ ni Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom, ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii.
Ọmọbinrin akẹkọọ-jade fasiti ẹni ọdun mẹrindilọgbọn ti wọn porukọ ẹ ni Umoren Iniubong, Ni afurasi ọdaran yii, Uduak Ukpan, da ẹmi ẹ legbodo nipinlẹ Akwa Ibom lọjọsi, lẹyin to fọgbọn tan an pe oun fẹẹ gba a siṣẹ, ṣugbọn to jẹ niṣe lo pa a lẹyin to fipa ba a lọpọ tan?
Awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ti ṣafihan afurasi ọdaran ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee yii, boroboro bii ajẹ tilẹ mọ ba ni Uduak n ṣalaye bo ṣe fiku oro pa ọmọ ọlọmọ ọhun, o ni ẹrọ abana-ṣiṣẹ, stabilaisa (stabilizer), loun la mọ ọmọbinrin naa lori.
Ṣe ẹni bimọ ọran ni i pọn ọn, Uduak ati baba ẹ, Frank Akpan, nileeṣẹ ọlọpaa patẹ wọn fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Uyo, nipinlẹ naa. Kọmiṣanna ọlọpaa ibẹ, Andrew Amiengheme, ni awọn ṣe bẹẹ tori ahesọ kan to n lọ nigboro pe afurasi ọdaran naa ti ku sahaamọ awọn ni, tabi wọn ti gbọna ẹyin sa lọ.
Aṣọ olomi ọsan kan ti wọn fi n polowo ẹgbẹ apaayan lo wọ sọrun, ohun ti wọn kọ sara aṣọ naa lede eebo ni “The Mudder Squad”.
Nigba ti wọn ni ko ṣalaye ohun to waye lọjọ iṣẹlẹ naa, Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, to kọja, ohun tọmọkunrin naa sọ gbomi loju eeyan, o ni:
Loootọ ni mo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i pe ko wa fun ifọrọwanilẹnuwo lori iṣẹ to loun n wa, mo si fun un ni adirẹsi. Nigba to de, mo yi ọrọ pada fun un, mo sọ fun un pe ṣe o le ṣiṣẹ bii akọwe ninu oko ti wọn ti n ṣọgbin egboogi oloro, ko maa ba wa ṣakọsilẹ ọja, o si gba, o ni iṣẹ loun saa n wa.
Ni mo ba sọ fun un pe mo n tan an ni o, ko si oko kan nibikan, ṣugbọn ma a ṣi ba a wa’ṣẹ, mo ni ko kọkọ jẹ ki n b’oun lo pọ na, o loun gba, ṣugbọn mọ gbọdọ lo rọba idaabobo, iyẹn kọndọọmu (condom), mo si ni ko buru.
Nigba ti mo ṣetan, ti mọ fẹẹ yọ kọndọọmu kuro, niṣe lo fa ibinu yọ, lo ba la stabilaisa to wa lẹgbẹẹ bẹẹdi mọ mi lori, o tun ge ika ọmọndinrin mi jẹ, ẹjẹ si jade lara mi.
Bemi naa ṣe gbe stabilaisa yẹn niyẹn, ni mo ba fibinu la a mọ oun naa lori, o kan mu idi lọ silẹ bẹẹ ni, ki n too mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ti dakẹ.
Mi o mọ pe o le gbabẹ ku. Mo gba a labara nikun boya o maa sọji, ṣugbọn ko mira rara. Ki i ṣe oun nikan ni mo ti ṣe iru iwa itanjẹ bẹẹ fun o, ṣugbọn tiẹ yii nikan lo bu mi lọwọ, oun nikan ni tiẹ la ẹmi lọ.
Mi o ni in lọkan lati pa a, ṣugbọn o ti ṣẹlẹ. Ti wọn ba ni mo jẹbi ipaniyan, mo ṣetan lati ku iku ẹ.
Nigba ti wọn bi i lere pe ko ṣalaye bata agunbanirọ atawọn oriṣiiriṣii dukia bii aṣọ, baagi, aago obinrin awọn to ti fẹtan mu bẹẹ ti wọn ba ninu yara ẹ, ati idi to fi lọọ sin ọmọ ọlọmọ loku oru sinu koto kuṣẹkuṣẹ kan lẹhinkule ile wọn, Akpan ni yatọ si iṣẹlẹ to waye yii, ko tun sẹlomi-in toun sin bẹẹ.
O ni mama oun lo ni bata agunbanirọ yẹn, oko si lawọn maa n wọ ọ lọ. “Emi ati aburo mi obinrin la ni awọn iwe.”
O tun ṣalaye pe baba oun ko mọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ naa, o ni baba agbalagba naa ko si nile, ko si mọ nipa boun ṣe sin oku Umoren.
O ni tori awọn aṣẹwo atawọn ọmọge to n ṣowo nabi nileewe ti foju oun ri mabo loun ṣe pinnu lati maa fẹtan mu awọn ọmọbinrin to ba ko sakolo oun, koun si maa fipa ba wọn lo pọ lati gbẹsan iya to ti jẹ oun.
Baba rẹ to jẹ oṣiṣẹ-fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba naa sọrọ, o loun o mọ pe iru iṣẹ buruku ati iwa ọdaran bẹẹ wa lọwọ ọmọ oun. O lawọn ṣẹṣẹ ko wa sile naa lati Abuja ni, oun loun si kọ ọ. O loun fara mọ ọn kijọba da sẹria to ba ofin mu fun un, tori ko si ohun to yẹ ki obi ṣe fọmọ toun o ṣe, oun tun tiraka lati ran wọn nileewe.
Ọjọ Furaidee yii kan naa ni wọn sinku Umoren ti Akpan pa. Tẹkun tomije lawọn eeyan rọ jade tẹle oku naa, ti wọn sin siluu Nung Ita Ikot Essien, nijọba ibilẹ Oruk Anam. Obitibiti epe ati oko ọrọ ni ọpọ awọn abanikẹdun to pesẹ sibẹ n rọjo sori ẹni to da ẹmi ọmọbinrin yii legbodo, bẹẹ ni wọn n woju Ọlọrun pe ko tete waa gbẹsan ẹjẹ Umoren lara awọn ti wọn ṣika pa a.