Gende meji ku ninu ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Ikẹrẹ-Ekiti

Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

 Ọkunrin meji lo dagbere faye lojiji ni Ọjọruu, Wẹsidee yii, ninu ija ajaku akata kan to ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji niluu Ikẹrẹ-Ekiti.

Ija to da jinnijinni silẹ niluu naa lo ṣẹlẹ ni deede aago mẹjọ alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ọdọ kan lo ko ara wọn jọ si ile igbafẹ kan to wa ni adugbo Odo-Ọja, niluu naa. Nibi ti wọn ti n ṣe faaji lawọn ọdọ kan ti ṣadeede jade, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn sọọọkan ile igbafẹ naa.

Wọn ni laarin iro ibọn to n dun ni kọṣẹkọṣẹ fun bii ogun iṣẹju lagbegbe ọhun ni awọn gende meji kan ti fara gbọta, ti wọn si doloogbe.

Bi ẹ ko ba gbagbe, oṣu to koja yii lawọn ọdọ mẹfa ku lọjọ kan ṣoṣo ninu ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ti wọn gbena woju ara wọn, eyi lo fa a tijọba ipinlẹ Ekiti fi kede ofin konile gbele fun bii oṣu kan gbako niluu naa.

Eyi to ṣẹlẹ kẹyin yii ni wọn sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ ni wọn sọ pe wọn wa lati ilu odikeji ti wọn waa gbẹsan pipa tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mi-in pa ọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’ ninu ija ti wọn ja loṣu to kọja ọhun.

Ija yii la gbọ pe o mu ki alaga ijọba ibile Ikẹrẹ-Ekiti, Ọnarebu Fẹmi Ayọdele, kọ lẹta sijọba ipinlẹ naa lati pe fun ofin konile gbele.

Apa kan lẹta naa ka pe: “Bi ipaniyan ṣe n gbilẹ si i niluu Ikẹrẹ-Ekiti, laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, ijọba ibilẹ naa ti mun ofin koni le gbele ti yoo bẹrẹ ni deede agogo mẹfa irọlẹ si mẹfa owurọ jade, bẹrẹ lati Ọjọbọ.”

“Ijọba n fi asiko yii parọwa si gbogbo olugbe ilu Ikẹrẹ-Ekiti ati agbegbe rẹ pe ki wọn bọwọ fun ofin ijọba, nitori ijọba ko ni i kuna lati fiya jẹ ẹnikẹni to ba tapa sofin.”

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ọlọpa yoo fi pampẹ ofin mu ẹnikẹni to ba tẹ ofin loju.

 

Leave a Reply