Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori ati kapa wahala ina gaasi to n bu gbamu, to si n pa awọn eeyan l’Abẹokuta, ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ti fofin de tita gaasi fawọn ileeṣẹ to n lo o fun iṣẹ kan tabi omi-in, fungba diẹ na.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu karun-un yii, ni aṣẹ naa waye. Kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ, Amofin Fẹmi Ogunbanwo, lo sọ eyi di mimọ l’Abẹokuta.
Ogunbawo sọ pe gbogbo awọn to ni nnkan i ṣe pẹlu afẹfẹ gaasi lawọn ẹka ileeṣẹ gbọdọ tẹle ofin yii, nitori ijọba ti gbe iṣẹ le ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ alaabo mi-in lọwọ lati maa lọ kaakiri, ki wọn si maa ṣọ ileeṣẹ yoowu to ba tun n lo afẹfẹ gaasi lasiko yii.
O ni ẹni tọwọ wọn ba tẹ to n tapa sofin aabo yii yoo fimu kata ofin gidi.
Yatọ si ileeṣẹ gaasi ti wọn ti kọkọ ti l’Omida, wọn tun ti ileeṣẹ kan naa pa lọjọ yii kan naa, nigba ti wọn ri i pe iṣẹ wọn le ṣakoba fun alaafia araalu.