Florence Babaṣọla
Ọmọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Babalọla Lekan, ti jade laye lasiko wahala kan to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji niluu Oṣogbo.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye, nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wahala naa ṣẹlẹ, ti iro ibọn si n dun lakọlakọ lagbegbe Gbaẹmu, si Balogun Aguro, kọja si Oluọdẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun oriṣii meji ni wọn kọju ija sira wọn nibẹ, ti wọn si n dọdẹ ara wọn kaakiri adugbo.
Lasiko wahala naa la gbọ pe ibọn ba Lekan to n gbe l’Ojule kẹẹẹdọgbọn, adugbo Johnmakay, lagbegbe Oluọdẹ, loju-ẹsẹ lo si jade laye.
Ọpalọla sọ siwaju pe ko sẹni to le sọ ni pato, awọn abala ẹgbẹ okunkun ti wọn yinbọn to pa Lekan ọhun, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe wọn ti gbe oku ọmọkunrin naa lọ sile igbokuu-si ti ileewosan UNIOSUN Teaching Hospital, niluu Oṣogbo.