Florence Babaṣọla, Osogbo
Awọn eeyan ilu Ifọn Orolu, nipinlẹ Ọṣun, fẹhonu han lọjọ Iṣẹgun lori bi wọn ṣe ni awọn eeyan alamuleti wọn, Ilobu, ṣe n doju ija kọ wọn, ti wọn si n ba dukia wọn jẹ ni gbogbo igba.
Adele ọba ilu naa, Oloye Agba Babatunde Oyetunji, lo ko awọn eeyan ilu naa sodi, ti wọn si gbe oniruuru patako ifẹhonu han lọwọ ninu eyi ti wọn ti n ke sijọba ipinlẹ Ọṣun lati tete da si ọrọ naa ko too bọ sori.
Lara awọn akọle to wa ninu iwe ọwọ wọn ni “Ọrẹ araalu ni Gomina Oyetọla, a fẹ alaafia”, “A ko fẹ ogun abẹnu lagbegbe wa”, “Gomina Oyetọla, mu gbogbo ileri ipolongo ibo to o ṣe ṣẹ” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Alukoro fun ẹgbẹ idagbasoke ilu Ifọn, Ọmọọba Jide Akinyọoye, fẹsun kan awọn eeyan ilu Ilobu pe ṣe ni wọn n ta ilẹ to jẹ ti Ifọn lagbegbe Ọpapa, ni Gbẹrẹ-Ọdọfin, fun awọn alaṣẹ ileewe gbogboniṣe aladaani kan.
O ni, “Fun apẹẹrẹ, wọn ti ba gbogbo awọn ile wa to wa labule Igbo Imiẹṣin jẹ patapata bayii, bẹẹ ni wọn ṣa ọmọ ilu wa kan, Akeem Mustapha, ti agboole Ajibọla, ladaa lori laipẹ yii.
“Lara idi ti wahala yii fi pọ ni pe ko si ọmọ ilu wa kankan ninu iṣejọba ipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ, ko sẹni to le gbẹjọ wa ro niwaju gomina, latigba ti ọba wa ti waja, awọn eeyan Ilobu ko fi wa lọkan balẹ rara, idaamu ni lojoojumọ.
“A n ke sijọba, labẹ idari gomina alaafia, Gboyega Oyetọla, lati tete dide si ọrọ yii, ki wọn kilọ fawọn ara Ilobu pe ki wọn kọwọ ọmọ wọn bọṣọ. A dupẹ lọwọ kọmiṣanna ọlọpaa, ṣugbọn a n beere pe ki wọn ba wa mu iṣipopada ba DPO ati DCO 1 to wa lagbegbe wa latari bi wọn ko ṣe nitara kankan si dugbẹdugbẹ ogun to n mi loke yii”
Ninu awijare tirẹ, Oludamọran lori ọrọ idajọ fun Ilobu-Aṣakẹ Descendants Union, Oloye Adegoke Ogunṣọla, sọ pe ilu Ilobu lo ni ilẹ ti wọn ta fun ileewe gbogboniṣe naa, o ni awọn eeyan Ifọn gan- an ni wọn ran awọn tọọgi lati lọọ hu patako nla tileewe naa ri mọbẹ, ti wọn si tun ko awọn to lọọ ri patako naa.
Adegoke ṣalaye pe lẹyin tawọn san ẹgbẹrun lọna ogun naira lawọn eeyan Ifọn too fi awọn eeyan Ilobu ti wọn ko silẹ. O ni awọn ko ṣekọlu si ẹnikẹni nitori eeyan alaafia ni gbogbo awọn to wa niluu Ilobu.