Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi mẹrin kan lori bi wọn ṣe yinbọn pa ọmọ ẹgbẹ awakọ kan, Adegboyegun Ademọla, nibi ti wọn ti n ṣepade lagbegbe Old Garrage, l’Akurẹ, ni nnkan bii osu meji sẹyin.
Awọn mẹrẹẹrin ọhun, Ọlọrunmaye Temitọpẹ, ẹni aadọta ọdun, Falọwọ Bisayọ, ẹni ọdun mẹtalelogoji, Afọlayan Kayọde, ẹni ọdun marundinlọgọta ati Akintade Busayọ ẹni ọdun marundinlaaadọta ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ ẹka tipinlẹ Ondo lọwọ tẹ niluu Ondo lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade tawọn ọlọpaa adigboluja ti wọn n pe ni Operation Puff Harder fi sita, wọn ni awọn afurasi ọhun ni wọn wa nidii bi wọn ṣe yinbọn pa Oloogbe Adegboyegun lasiko rogbodiyan to waye lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta, ọdun ta a wa yii.
Ibọn mẹrin ati ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry tí wọn ko ti i gba nọmba si wa lara nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn tọwọ tẹ ọhun.
Awọn nnkan ija oloro naa ni wọn lọọ hu jade ninu ile akọlu kan to wa ni Igoba, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, nibi tawọn janduku ọhun n ko wọn pamọ si.
Ọkan ninu wọn, Busayọ Akintade ni wọn lo n ṣe atọna bi wọn ṣe n ri awọn nnkan ija oloro naa ra. Awọn ọlọpaa ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn yooku mu.