Ọba Akiolu bẹ orileede Gẹẹsi lati ran Naijiria lọwọ lori ipenija eto aabo

Faith Adebọla, Eko

Ọba ilu Eko, Riliwan Babatunde Akiolu, ti parọwa si orileede Britain lati ma ṣe wo Naijiria niran lori ipenija eto aabo to mẹhẹ lasiko yii, o ni ki wọn ran wa lọwọ lati tete fopin si i.

Akiolu sọrọ yii nigba to n gbalejo Igbakeji aṣoju orileede Britain, Ọgbẹni Ben Llewellyn Jones, laafin rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.

Ọba alaye naa sọ pe loootọ loun nigbagbọ pe iṣoro aabo yii ṣi maa dohun igbagbe, to si maa dọrọ itan to ba ya, ṣugbọn gbogbo isapa to ba yẹ nijọba ati araalu gbọdọ sa, a si tun gbọdọ wa iranwọ ati atilẹyin awọn orileede to ti goke agba, ti wọn si ti la iru iṣoro yii kọja, lati kun wa lọwọ.

Nigba to n fesi, Ọgbẹni Jones ni ọrọ Naijiria jẹ orileede Britain logun, awọn si maa ṣeranwọ to yẹ, paapaa lati mu ki ọrọ-aje to n ṣojojo tubọ ru gọgọ si i.

Jones ni “O wu mi lati tubọ mojuto bi ajọṣe to dan mọran ṣe maa wa lori ọrọ-aje ati okoowo ṣiṣe, a maa ṣatilẹyin to ba yẹ ki alaafia, ifọkanbalẹ, ipese iṣẹ, ati mimu ki ọrọ-aje ru gọgọ wa lorileede Naijiria. A maa ṣiṣẹ lori mimu awọn nnkan idena ti ko jẹ ki ajọṣe olokoowo rọrun, kuro.”

Jones ni ko si bawọn ṣe le ko iyan Naijiria kere tori ninu awọn orileede ti Britain ti n ṣe kara-kata ju lọ, Naijiria lo wa ni ipo keji, leyii to fihan pe awọn ko le fọwọ rọ ọ sẹyin, ohun to de ba oju ti de ba imu ni, ọrọ Naijiria kan awọn gbọngbọn.

O ni oriṣii awọn okoowo igbalode nla kan maa too balẹ si Naijiria latọdọ awọn laipẹ.

Leave a Reply