A ko ni ilẹ kankan ta a maa fawọn janduku apaniyan ti wọn n pera wọn ni darandaran-Akeredolu

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ko fọrọ awọn darandaran ṣawada lasiko yii rara, o ti kilọ fun Mallam Garba Shehu, Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, pe ko ṣọra ẹ, ko si ṣọ ohun to maa maa tẹnu ẹ jade, o lawọn gomina kọja ẹni arifin latọdọ oṣiṣẹ Aarẹ eyikeyii, bẹẹ si lawọn o ni i yọnda abala ilẹ pinniṣin fawọn Fulani darandaran ni gbogbo ilẹ Yoruba ati ni Guusu orileede yii.

Oluranlọwọ gomina lori akanṣe iṣẹ, Ọgbẹni Doyin Ọdẹbọwale, lo fi atẹjade kan lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, eyi ti Gomina Akeredolu fi fesi sọrọ ti Garba Shehu kọ lorukọ Aarẹ Muhammadu Buhari lori ipinnu awọn gomina iha Guusu ilẹ wa ti wọn lawọn fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba lagbegbe awọn.

Akeredolu ni Garba Shehu kere si ẹni to maa maa ṣepinnu fun Aarẹ lori awọn ọrọ to ta koko bii eyi ti wọn n sọ yii, bẹẹ si ni ko laṣẹ lati maa gbe awọn alakalẹ ijọba lelẹ lorukọ ijọba apapọ fawọn gomina.

Apa kan atẹjade Akeredolu naa ka pe: “Ọgbẹni Garba Shehu fi atẹjade kan lede fawọn oniroyin eyi to fẹ ka gbagbọ pe ero Aarẹ Muhammadu Buhari lori wahala awọn agbẹ atawọn darandaran lo wa ninu ẹ, ati pe awọn aba ti wọn kọ sibẹ lo maa yanju iṣoro yii.

O tun sọrọ nipa ipinnu adaṣe kan to ni Buhari ṣe lati ṣi ọna silẹ fun kikọ awọn ibudo ifẹranjẹko ati titun awọn igbo ọba ṣe gẹgẹ bii ojuutu gidi si iṣoro awọn darandaran to di lemọlemọ yii.

‘‘Gbogbo ẹni to ba ṣakiyesi bi ọkunrin Garba yii ṣe n sọrọ, ati bawọn eeyan bii tiẹ naa ṣe n sọrọ, maa ri i pe ọrọ itanra-ẹni-jẹ ati irọ gbuu to le tanna ran yanpọnyanrin lọrọ wọn, ko si ṣoro lati mọ pe iromi wọn to n jo lori omi yii, onilu rẹ n bẹ nisalẹ odo, awọn ọta ilẹ wa ni wọn n gbẹnusọ fun.

‘‘Ọgbẹni Garba ni lati bọ si gbangba ko sọ awọn to ran an niṣẹkiṣẹ to n jẹ, tori o daju pe ki i ṣe Aarẹ. Ko le maa lugọ sẹyin ika kan ko ro pe ko sẹni to ri oun, awọn ọrọ to n jade lẹnu wọn yii fihan pe wọn n ṣiṣẹ fawọn kan ni.”

Akeredolu ni o ya oun lẹnu gidi lati gbọ ninu atẹjade ọhun pe Aarẹ ti fọwọ si awọn aba ti Minisita feto ọgbin, Alaaji Sabo Nanono gbe siwaju rẹ nigba ti awọn aba tawọn gomina taraalu dibo yan sipo ṣi wa niwaju Aarẹ ti wọn ko ti i fọwọ si i.

Gomina Akeredolu ṣalaye siwaju si i pe: “Ọgbẹni Garba sọ pe ikede tawa gomina mẹtadinlogun iha Guusu ilẹ wa ṣe ko tẹwọn loju ofin, ko bofin mu to, ṣugbọn ipinnu awọn eeyan kan lati gba ilẹ awọn baba nla ẹni-ẹlẹni, ki wọn fa a le awọn eeyan tiwọn lọwọ, awọn eeyan wọn apaayan to n gbebọn-rin atawọn mọlẹbi wọn, ki wọn pese ileewosan nnkan ọsin, omi fawọn ẹran ọsin, ki wọn si kọle ati ileewe fawọn darandaran wọnyi lawọn igbo ọba, Garba ko si ri eyi bii iwa ajagungbalẹ, iwa oju dudu ti ko yatọ si tawọn oyinbo amunisin aye ọjọun.”

Nipari ọrọ rẹ, Akeredolu ni: “Ọrọ ati iwa Garba fihan pe agbodegba ẹda kan ni. Awọn eeyan bii tiẹ to ku ti wọn n ronu, ti wọn n la ala bawọn ṣe maa mu ẹya mi-in lẹru gbọdọ taji loju oorun wọn. Ko si abala ilẹ kan, bo ti ko kere to, ibaa jẹ eyi to wa lakọọlẹ tabi tijọba, ni gbogbo agbegbe ilẹ Yoruba, ati ni agbegbe Guusu pata, ta a maa fi silẹ fawọn janduku apaayan ti wọn dibọn pe ara wọn ni darandaran.”

Leave a Reply